Ozoro, Niger Delta

PANDEF ń béèrè fún ìwádìí lórí ẹ̀sùn ìkọlù àti ìfipábánilòpọ̀ àwọn obìnrin níbi Ọdún Ozoro

Àjọ Pan Niger Delta Forum (PANDEF) ti ké sí àwọn aláṣẹ láti ṣe ìwádìí kánjúkánjú lórí ẹ̀sùn ìfìyàjẹ àti ìfipábánilòpọ̀ àwọn obìnrin lásìkò ọdún ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yí ní Òzórò, ní Ìpínlẹ̀ Delta.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ fún àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, Olóyè Dókítà Obiuwevbi Ominimini fọwọ́ bọ̀, ẹgbẹ́ tí ó ga jùlọ fún ọ̀rọ̀ òṣèlú àti àwùjọ ní Ẹkùn Gúúsù-Gúúsù (Niger Delta) rọ Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà láti gbé ìgbésẹ̀ kánkán kí wọ́n lè fìyà jẹ àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú ìwà náà.

PANDEF tẹnumọ́ ọn pé kò sí àṣà ìbílẹ̀ kankan tí ó gbọdọ̀ tẹ ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú tí ó wà nínú òfin orílẹ̀-èdè lójú, wọ́n sì kìlọ̀ pé a kò gbọdọ̀ fi ọdún àṣà ṣe àwáwí fún ìwà tí ó ń tàbùkù sí ẹ̀tọ́ àti iyì ọmọ ènìyàn.

“Lábẹ́ ipò kí ipò, kò sí àṣà ìbílẹ̀ kankan tí ó gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú wewu nínú àwùjọ, ìjọba, tàbí agbègbè èyíkéyìí,” ni àtẹ̀jáde náà sọ.

Ẹgbẹ́ náà ṣàkíyèsí pé Òzórò, èyí tí í ṣe olú-ìlú fún Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Isoko, ti jẹ́ agbègbè tí àlàáfíà ti jọba fún ìgbà pípẹ́, tí ó sì ń gba àwọn ọmọ onílẹ̀ àti àwọn àlejò mọ́ra, pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Ìmọ̀-ẹ̀rọ ti Ìpínlẹ̀ Delta. Ó tẹnumọ́ ọn pé gbogbo olùgbé ibẹ̀, yálà nípa ìbínilẹ́ tàbí ẹ̀sìn, ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ tí Òfin Nàìjíríà fàyè gba fún wọn.

Nígbà tí wọ́n ń dá lẹ́bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, PANDEF yìn Ọba ìlú Òzórò àti Ààrẹ pátápátá fún àwùjọ náà fún ìgbésẹ̀ kíákíá tí wọ́n gbé láti fọhùn lòdì sí ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ náà.

Síbẹ̀síbẹ̀, ẹgbẹ́ náà tẹnumọ́ ọn pé àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ gbọdọ̀ fojú wé bá òfin láìfàkòkòṣòfò kí ó lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn. “Ayé ti kúrò níbi irúfẹ́ ìwà ìkà àti òkùnkùn bẹ́ẹ̀. Gbogbo àṣà ìbílẹ̀ gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin orílẹ̀-èdè,” ni àtẹ̀jáde náà fi kún un.

Ẹgbẹ́ náà tún ké sí àwọn adarí àwùjọ náà láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó múná dóko láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú, wọ́n sì ṣàkíyèsí pé Òzórò máa ń fi yangàn pé àwọn ní àwọn adarí tí wọ́n kàwé tí wọ́n sì lajú.

PANDEF tún tẹnumọ́ ìpinnu rẹ̀ láti dáàbò bò ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, wọ́n sì rọ àwọn aláṣẹ láti rí i dájú pé àwọn tí a fìyà jẹ rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí wọ́n sì tún rí i dájú pé àlàáfíà àti orúkọ rere àwùjọ náà kò bàjẹ́.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment