Owó epo rọ̀bì wálẹ̀ lábẹ́ ọgọ́rùn-ún dọ́là lẹ́yìn tí Trump dá ìkọlù orílẹ̀-èdè Iran dúró
Iyẹ́ owó epo rọ̀bì já sílẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ Ajé lẹ́yìn tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump, sọ pé òun ti paṣẹ pé kí wọ́n dá ìkọlù tí òun halẹ̀ láti ṣe sí àwọn ilé-iṣẹ́ agbára orílẹ̀-èdè Iran dúró lẹ́yìn “ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó dán mọ́rán tó sì mú èso jáde” pẹ̀lú ìlú Tehran.
Trump sọ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Iran “ti ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó dán mọ́rán tó sì mú èso jáde ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn nípa bí a ṣe lè fi òpin pátápátá sí ìjà wa ní Àárín Ìlà-oòrùn,” Trump ló kọ èyí pẹ̀lú lẹ́tà ńlá ní kùtùkùtù ọjọ́ Ajé lórí ojú òpó Truth Social rẹ̀.
“Láti inu bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà ṣe ń lọ,” èyí tí “yóò tẹ̀síwájú jákèjádò ọ̀sẹ̀ yí, mo ti paṣẹ fún Ẹ̀ka tí ó ń rí sí Ọ̀rọ̀ Ogun láti sún gbogbo ìkọlù ológun èyíkéyìí lórí àwọn ilé-iṣẹ́ iná àti ohun èèlò agbára orílẹ̀-èdè Iran síwájú fún ọjọ́ márùn-ún, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ìpàdé tí ó ń lọ lọ́wọ́ yí bá ń yọrí sí rere,” ó fi kún un.
Àgbá epo West Texas Intermediate, èyí tí ó jẹ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n fún Àríwá Amẹ́ríkà, ń tà ní owó tí ó dín ní àádọ́rùn-ún dọ́là, tí ó ti já sílẹ̀ pẹ̀lú iye tí ó jù ìdá méje nínú ọgọ́rùn-ún lọ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọjà ìṣòwò gbé pẹ́ẹ́lì ní ìbẹ̀rẹ̀ títà àti rírà.
Iyẹ́ owó epo rọ̀bì ti lọ sókè pẹ̀lú bíi ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún nínú oṣù yí láti ìgbà tí ìjà ti bẹ̀rẹ̀ ní Àárín Ìlà-oòrùn.
Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́yìn ìkéde ìdádúró ìjà tí Trump ṣe ní ọjọ́ Ajé, iye epo Brent já sílẹ̀ pẹ̀lú ìdá tí ó jù mẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún lọ ní àkókò ìṣòwò náà, tí ó sọ̀kalẹ̀ dé owó kékeré bíi dọ́là mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún fún àgbá kan, èyí tí ó wá rọ̀ sílẹ̀ lábẹ́ ọgọ́rùn-ún dọ́là fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọjọ́ kọkànlá oṣù Kẹta.
Ọ̀pá ìdiwọ̀n tí Amẹ́ríkà, West Texas Intermediate (WTI) tún rọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ìdá mẹ́tàlá àti ààbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún (13.5%), tí ó sọ̀kalẹ̀ sí dọ́là márùndínláàádọ́rùn-ún àti sẹ́ńtì méjìdínlọ́gbọ̀n ($85.28).
Ṣùgbọ́n, ní ǹkan bíi aago mọ́kànlá ààbọ̀ àárọ̀ (1130 GMT), epo Brent tún lọ sókè dé ìpele dọ́là mẹ́rinlélọ́gọ́rùn-ún ($104) fún àgbá kan, nígbà tí WTI wà ní àádọ́rùn-ún dọ́là àti sẹ́ńtì márùndínláàádọ́ta ($90.55).
Iye epo Brent ti lọ sókè kíkankíkan pẹ̀lú ìdá tí ó lé ní ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣòro tí ó wà ní Àárín Ìlà-oòrùn, tí ó sì gùn sókè dé ǹkan bíi dọ́là méjìlá-lé-lọ́gọ́rùn-ún ($112) fún àgbá kan ní ọjọ́ Ajé, ṣáájú ìkéde tí Trump ṣe.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

