NYSC Sẹ́ Ọ̀rọ̀ Ìwé Pélébé Tó Gba Àwọn Kọ́pà Nímọ̀ràn Láti San Owó ìràpadà

Àjọ Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Orílẹ̀-èdè, (National Youth Service Corps (NYSC) ti sọ pé ọwọ́ àwọn kò sí nínú ìwé pélébé kan tó ń káàkiri lórí ẹ̀rọ ayélujára, èyí tó ń gba àwọn ọmọ kọ́pà nímọ̀ràn láti san owó ìdáǹdè tí wọ́n bá jí wọn gbé. Wọ́n ṣàpèjúwe ìwé náà gẹ́gẹ́ bí ayédèrú àti èyí tí kò bá ìlànà ààbò wọn mu rárá.

Nínú àtẹ̀jáde kan, Àjọ Olùdarí NYSC sọ pé irú ìwé bẹ́ẹ̀ ni olùdámọ̀ràn kan gbé wá ní ọdún 2021 ṣùgbọ́n tí wọ́n kò fọwọ́ sí i tàbí tẹ́wọ́ gbà á rárá lábẹ́ ètò náà. Ó tẹnu mọ́ ọn pé ìwé tí ń káàkiri báyìí kì í ṣe ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ NYSC, ó sì yẹ kí gbogbo ènìyàn fojú fò ó dá pátápátá.

Àtẹ̀jáde náà kà pé: “Àjọ Olùdarí fẹ́ fi yé yín kedere pé ìwé tí ń káàkiri náà kì í ṣe ìtẹ̀jáde àṣẹ ti NYSC, kò sì dúró fún ìlànà Àjọ náà nípa ààbò àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn ọmọ Kọ́fà.”

NYSC tún fi ìdí ìfọkànsìn rẹ̀ múlẹ̀ sí ìlera àti ààbò àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn ọmọ kọ́fà, ó sì fi dá wọn lójú pé òun ń báa lọ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti mú ààbò pọ̀ sí i àti láti dojú kọ àwọn ewu tó ń yọjú.

Àtẹ̀jáde náà fi kún un pé: “Tiwa ni Nàìjíríà; Nàìjíríà la ń sìn.”

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment