Kókó tí ó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa Àjọ̀dún Ọlọ́jọ́ ní Ilé-Ifẹ̀.
Àjọ̀dún Ọlọ́jọ́ (Olojo Festival), tí ó fìdí múlẹ̀ nínú àròsọ Yorùbá, jẹ́ àjọ̀dún ẹ̀sìn àti àṣà, tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìsẹ̀lẹ̀ Odùduwà àti dídá ayé.
Wọ́n gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan pàtàkì nínú àṣà ìran Nàìjíríà, tí ó ń fún àwọn arìnrìn àjò ní ànfààní láti rí oríṣiiríṣi àṣà Nàìjíríà tí ó kún fún ọ̀rọ̀.
Àjọ̀dún Ọlọ́jọ́ jẹ́ àjọ̀dún àṣà àti ẹ̀sìn ọdọọdún ní Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Nàìjíríà.
Ó ń bọ̀wọ̀ fún àkọ́kọ́ dáyé àti àwọn orísun àbàtàwá ìran Yorùbá.
Orúkọ “Ọlọ́jọ́” túmọ̀ sí “Ọjọ́ Ìmọ́lẹ̀ Àkọ́kọ́” (The Day of the First Dawn) ó sì ń ṣe ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú àròsọ Yorùbá, bíi ìsẹ̀lẹ̀ àwọn òrìṣà sí ayé àti dídá ayé.
Ìgbésẹ̀ pàtàkì kan wà nínú rẹ̀ tí Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀, (The Ooni of Ife) aṣáájú ẹ̀mí àwọn Yorùbá, máa ń lò, ẹni tí yóò wà nínú ìyàrá ìkọ̀kọ̀ fún ọjọ́ méje kí ó tó yọ síta láti wọ Adé Aàrẹ (Aare Crown) mímọ́—ohun àmúlò tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ adé Odùduwà, fún ìparí gbàgede náà.

Adé Aàrẹ lórí Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀, Ọba Adéyeyè Ẹnitan Ògúnwùsì ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ó jáde láti inú ìyàrá ìkọ̀kọ̀ ọjọ́ méje. Oríṣun àwòrán – Abayomi Adebayo.
Ìyàrá ìkọ̀kọ̀ ọjọ́ méje (Seven-day Seclusion) náà jẹ́ àsìkò ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀mí nígbà tí Ọọ̀ni máa ń fi ara rẹ̀ pamọ́ kúrò níwájú gbogbo ènìyàn bí ó ti ń ṣe àṣàrò, tí ó sì ń gbàdúrà títí di ìgbà tí ọjọ́ méje náà yi o pé.
Ní èdè olùyàwòrán Nàìjíríà Abayomi Adebayo (@theadebayomi lórí Instagram), “Àjọ̀dún náà jẹ́ ayẹyẹ àṣà, ìṣe àti ẹ̀mí tí ó lágbára pẹ̀lú Ọọ̀ni tí ó jáde láti inú ìyàrá ìkọ̀kọ̀ ọjọ́ méje, ìsọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tẹ̀mí ọdọọdún tí ó máa ń ṣe láti bá Ẹlẹ́dùmarè àti àwọn ẹ̀mí àwọn baba ńlá rẹ̀ sọ̀rọ̀.”
Ìfìwéránṣẹ́ rẹ̀ lórí Instagram jẹ́ àkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì àjọ̀dún náà ní bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Ọọ̀ni jáde láti inú ìyàrá ìkọ̀kọ̀ ọjọ́ méje sí Ìwẹ̀nùmọ́ Àwùjọ (Community Cleansing), èyí tí ó tẹ̀lé e pẹ̀lú Ìrìn Àjò Adé Aàrẹ Ọjọ́ Òkè Mògún, àti Ọjọ́ Ìbílẹ̀, níbi tí ó ti máa ń lọ sí àárín gbùngbùn àwùjọ, èyí sì ni ìgbà tí àwọn àgbà àti àwọn oníṣègùn bá a kí.
Lẹ́yìn èyí, ìbẹ̀wò sí àwọn ilé-ọba àti ìrìn-gbèdéke ìkẹhìn gba àwùjọ tó sún mọ́bẹ̀ wọ̀nyí wáyé.
Abayomi ṣàpèjúwe ìlànà yìí gẹ́gẹ́ bí títẹ̀lé ara wọn tí ó ṣàpẹẹrẹ ìṣọ̀kan láàrin àwọn ènìyàn àti ọ̀rọ̀ àṣà tí ó kún fún àwọn ènìyàn Ilé-Ifẹ̀, àwọn ọmọ ọmọ Odùduwà.
Àjọ̀dún náà ń ṣe ayẹyẹ ìṣẹ̀dá àtọ̀runwá, ó sì sàmì sí ọjọ́ tí àwọn òrìṣà sọ̀ kalẹ̀ wá sí ayé, tí Ọlọ́run sì dá ènìyàn. Ó tún ń ṣe ayẹyẹ àwọn orísun àbàtàwá nítorí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìbẹ̀rẹ̀ àti ìtànkálẹ̀ ìran Yorùbá, tí wọ́n ti tọpinpin rẹ̀ padà sí Ilé-Ifẹ̀, orísun àwọn Yorùbá.
Ó tún ṣàpẹẹrẹ pàtàkì Ògún, òrìṣà Irin, àkọ́bí Odùduwà, baba ńlá àwọn Yorùbá.
Àjọ̀dún yìí ní àwọn apá kan pàtàkì tí ó para pọ̀ di gbogbo ayẹyẹ náà, bíi Ìyàrá Ìkọ̀kọ̀ Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ níbi tí ó ti máa ń yẹra fún àwùjọ fún àsìkò ìgbàròyé tẹ̀mí, láti bá àwọn baba ńlá sọ̀rọ̀ àti láti bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀
Apá pàtàkì mìíràn ni Adé Aàrẹ—Ọọ̀ni máa ń wọ adé mímọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àmì àṣẹ àti ìsopọ̀ sí ọ̀run.
Àwọn apá pàtàkì mìíràn tún ni àwọn ìṣe àṣà àti ìrìn àjò àwọn ènìyàn tí ó ní nínú àwọn ayé, àwọn eré àṣà, ìrìn àjò àṣà, àti ayẹyẹ ìbọ àwọn baba ńlá.
Àjọ̀dún yìí tún ní ìkópa àwùjọ nínú rẹ̀ bíi Àjọ̀dún Adìre Hub (Adire Hub Fiesta) àti wíwá àwọn onítalẹ́ǹtì àṣà,(Cultural Talent Hunt) èyí tí ó ń fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àṣà lágbára.
Ní kukuru, Àjọ̀dún Ọlọ́jọ́ jẹ́ apá kan pàtàkì nínú àṣà ìran Nàìjíríà, àti ìhà kan tí ó ṣe pàtàkì nínú àṣà Yorùbá, ó ń fúnni ní òye sí oríṣiiríṣi àṣà Nàìjíríà tí ó kún fún ọ̀rọ̀. Ó tún jẹ́ àsìkò tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún, fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tẹ̀mí, tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìṣẹ̀dá ayé àti wíwàláàyè ènìyàn
Àjọ̀dún Ọlọ́jọ́ ti ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ogún (20) oṣù kẹsán títí di ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n (29) oṣù kẹsán ọdún 2025. Àkòrí rẹ̀, “Ìdàgbàsókè Ìrìn-àjò Afọwọ́ṣe Tí ń Yípadà Pẹ̀lú Àwọn Àjọ̀dún Àwùjọ” jẹ́ àfihàn àkópọ̀ pàtàkì àjọ̀dún náà.
Gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni ti sọ, ìyàrá ìkọ̀kọ̀ ọsẹ̀ kan náà jẹ́ nípa pípa àṣà mọ́ àti gbígbà àwọn ìbùkún sí orí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń rán gbogbo ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Odùduwà létí láti wà ní ìṣọ̀kan, ní àlàáfíà, àti láti máa tẹ̀síwájú nínú wíwá Nàìjíríà tí ó tóbi jù.
Nínú ìfìwéránṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Premium Times, wọ́n ròyìn pé ìrìn-àjò ìyàrá ìkọ̀kọ̀ Ọọ̀ni, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, parí ní ọjọ́ keje rẹ̀, Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n (27), pẹ̀lú Ayẹyẹ Ìparí Gbàgede Àjọ̀dún Ìkẹhìn (Festival Grand Final Official Ceremony), Ọjọ́ Òkè Mògún (the day of Òkè Mògún ) àti Ìrìn Àjò Àṣà Aàrẹ (Aare Cultural Procession).
Lẹ́hìn náà, wọ́n ti àjọ̀dún náà pa pẹ̀lú Ọjọ́ Àjóyọ̀, Ìpàdé Ìgbàlejò Ọba Gbàgede, (Ojo Ajóyo, the Grand Royal Reception) tí ó ní Àfihàn Ìṣẹ́ṣúpọ̀ Àṣà Adìre Ọòdúa (Adire Oodua Cultural Exchange Exhibition) àti Ẹ̀bùn Ifẹ̀ fún Iṣẹ́ Àwùjọ 2025 (Ife Award for Community Service) ní ọjọ́ kẹjọ lé lógún (28) Oṣù Òwéwé, pẹ̀lú Ìrìn Àjò Àṣà Ilé-Baba ńlá Onírìṣà (Onirisa’s Ancestral Home Traditional Procession) àti Wíwá Àwọn Onítalẹ́ǹtì Àṣà (Cultural Talent Hunt) ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n (29) Oṣù Òwéwé ọdún 2025.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

