Ìpayà Ńlá Ní Pápá Ọkọ̀ Òfuurufú Akúrẹ́ Bí Àwọn Ọ̀daràn Ṣe Wo Ojú-ọ̀nà Ọkọ̀
Ìpayà gidi ni ó bá àwọn òṣìṣẹ́ àti èrò ní pápá ọkọ̀ òfuurufú Akúrẹ́ ní ìpínlẹ̀ Òndó, lẹ́yìn tí àwọn tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọ̀daràn lé àwọn àgbẹ̀ kúrò lóko wọn wọ inú ojú-ọ̀nà tí ọkọ̀ òfuurufú ń gbà fò sókè (runway).
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé lọ́jọ́ Àìkú nígbà tí wọ́n rí obìnrin kan àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin díẹ̀ tí wọ́n ń sáré látinú oko wọn tó wà lẹ́yìn odi pápá ọkọ̀ náà kọjá sí etí ojú-ọ̀nà ọkọ̀ òfuurufú.
Àwọn àgbẹ̀ wọ̀nyí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn ọkùnrin kan lórí alùpùpù tí wọ́n ń lé wọn bọ̀.
Àwọn akóso ètò ọkọ̀ òfuurufú (Air Traffic Controllers) tí wọ́n wà nínú ilé ìṣọ́ wọn ti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí àwọn oṣìṣẹ́ aláàbò láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Èyí mú kí àwọn oṣìṣẹ́ Aviation Security (AVSEC) àti àwọn ọmọ ogun ojú òfuurufú (Air Force) bọ́ sínú igbó tó wà nítòsí, iṣẹ́ wọn sì yọrí sí rere bí wọ́n ṣe mú afasura mẹ́rin.
Wọ́n ti gbé àwọn tí wọ́n mú náà lọ sí ibùdó ọlọ́pàá (Area Command) fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò láti mọ ẹni tí wọ́n jẹ́ gangan.
Òṣìṣẹ́ kan láti àjọ NAMA jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé ẹ̀mí àwọn òṣìṣẹ́ wà nínú ewu, ó sì bẹ ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn ààbò ní pápá ọkọ̀ náà.
Olùdarí àjọ FAAN, Ìyáàfin Olubunmi Kuku, fèsì sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé àwọn ti fọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá àti ọmọ ogun láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ó tẹ̀síwájú pé ìdí nìyí tí ìjọba àpapọ̀ fi ń tẹra mọ́ títí odi yí pápá ọkọ̀ òfuurufú ká láti rí i pé ààbò kún rẹ́rẹ́.
Orísun – Iroyin Vanguard
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

