Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn Ṣe Ìdárò Àwọn Tó Kú Nínú Ìjàǹbá Mọ́tò Anthony Joshua
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn ti kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn mọ̀bí, ọ̀rẹ́, àti àwọn ẹgbẹ́ àwọn tí ó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàǹbá mọ́tò tó bani nínú jẹ́ kan tí ó ṣẹlẹ̀ sí òléwájú nínú ìjàmúdu boxing lágbàyé, Anthony Joshua.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ti wí, Anthony Joshua fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàǹbá náà ní ọjọ́ Ajé, ṣùgbọ́n ó bọ́ lọ́wọ́ ikú.
Atẹ̀jáde kan tí Kayode Akinmade, Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn lórí Ìròyìn àti Ìlànà fọwọ́ bọ̀, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìwádìí àkọ́kọ́ fi hàn pé àwọn ọkùnrin àjèjì méjì ni wọ́n kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ níbi ìjàǹbá náà.
Wọ́n ti gbé òkú wọn lọ sí ilé-ìgbòkú ní Ìlú Sághámù.
Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò tí wọ́n wà nínú ọ̀wọ̀-ọkọ̀ (convoy) Anthony Joshua ni wọ́n gba òun àti awakọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ti gbé wọn lọ sí ilé-ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́.
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun tó bani nínú jẹ́ àti ohun tó dunni mọ́ni gan-an, pàpà jù lọ fún pàdánù ẹ̀mí tí ó ṣẹlẹ̀, nígbà tí àwọn mìíràn farapa yán-án-yán tí wọ́n sì ń gba ìtọ́jú.
Nítorí náà, wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣọ́ra gidigidi kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin ojú-pònà, pàpà jù lọ ní àsìkò ọdún yìí tí ọkọ̀ máa ń pọ̀ lójú títì.
Wọ́n tún rọ àwọn òṣìṣẹ́ tí ń bójútó títì (Road Safety) àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò mìíràn láti túbọ̀ mú iṣẹ́ wọn ní kunkun káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti rí i pé ẹ̀mí àti dúkìá ará ìlú wà nínú ààbò.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

