Tunji Olubunmi, Minista fun eto orile ede

Ìjọba Àpapọ̀ Kéde Ọjọ́ ọjọ́rú Àti Ọjọ́ Ẹtì Bíi Ọjọ́ Ìsinmi Láti Ṣe Ayẹyẹ Òǹdùnnú Eid-el-Fitr

Last Updated: March 17, 2026By Tags: , ,

Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ti kéde ọjọ́ ọjọ́rú, ogúnjọ́, oṣù Kẹta (March 19), àti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kẹta ọdún 2026 (March 20), gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi fún gbogbo ènìyàn láti ṣe ayẹyẹ Òǹdùnnú (Eid-el-Fitr), tó jẹ́ òpin oṣù mímọ́ ti Ramadánì.

Akọ̀wé àgbà nínú ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn abẹ́lé, Magdalene Ajani, ni ó fọwọ́ sí ìfilọ̀ yìí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, Mínísítà fún ọ̀ràn abẹ́lé, Olubunmi Tunji-Ojo, ni ó ṣe ìkéde ọjọ́ ìsinmi Òǹdùnnú náà ní orúkọ ìjọba àpapọ̀.

Tunji-Ojo bá àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí yọ̀ fún àṣeyọrí píparí oṣù mímọ́ Ramadánì, ó sì rọ̀ wọ́n láti tẹ̀síwájú nínú àwọn ìwà rere bíi ìfẹ́, ìwà ọ̀làwọ́, àlàáfíà, ìfaradà, àti ìrúbọ tí wọ́n kọ́ lásìkò oṣù mímọ́ náà.

Mínísítà náà tún rọ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti lo àsìkò ọdún yìí láti gbàdúrà fún àlàáfíà, ìṣọ̀kan, àti ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè síwájú sí i. Ó rọ àwọn ará ìlú láti ṣayẹyẹ pẹ̀lú ọgbọ́n, kí wọ́n sì ṣàánú fún àwọn aláìní láàárín àwùjọ.

Ìjọba àpapọ̀ tún tẹnu mọ́ ọn pé àwọn pinnu láti rí i pé ìṣọ̀kan àti ìgbé-ayé pẹ̀lú àlàáfíà fìdí múlẹ̀ láàárín gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tíì rí òṣùpá tuntun, àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí kárí ayé ń dúró de rírí òṣùpá láti fòpin sí ààwẹ̀ ọdún 1447 AH yìí.

Ní àkókò kan sẹ́yìn, ìròyìn láti TVC News ti sọ pé Alájì Abubakar Sa’ad III, Sultan ti Sokoto, ti jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé ọjọ́rú, ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejì ọdún 2026 (February 18), ni ọjọ́ àkọ́kọ́ fún ààwẹ̀ Ramadánì ní orílẹ̀-èdè yìí.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment