Ìbọn ni Frankfurt gbé wá sójú ìjà ìkúku Galatasaray tí wọ́n sì lù wọ́n ní àlùbòmí pẹ̀lú àmì ayò 5-1
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Eintracht Frankfurt ti tì Galatasaray sínú omi òkun bí wọ́n ṣe lù wọ́n ní pọ́n-po lẹ́yìn ọrùn pẹ̀lú àmì ayò márùn-ún sí òkàn ṣoṣo.
Fún àwọn ọ̀sẹ̀, Eintracht Frankfurt ti ń retí èyí — ìfarahàn àkọ́kọ́ wọn nínú Champions League, níbi tí wọ́n ti jẹ́ àwọn tí a kò fojú sí rárá.
Pẹ̀lú bí ó ti jẹ́ pé, pápá ìṣeré kún tìkún fún àwọn alátakò wọn àkọ́kọ́, Galatasaray. Àyíká náà kún fún ìgbádùn nínú àwọn àwọ̀ dúdú àti funfun tí ó jẹ́ àwọn àwọ̀ ẹgbẹ́ Eintracht.
Àyíká tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bú gbàkì lẹ́yìn ìṣẹ́jú méjì péré. Nathaniel Brown gba bọ́ọ̀lù náà lọ́wọ́ Leroy Sané ní apá Gala, ó sì gbé e fún Ansgar Knauff. Olùṣọ́nà Istanbul, Ugurcan Cakir, gbìyànjú láti tẹ̀ bọ́ọ̀lù Knauff lọ́wọ́ sí igun láti ìwọ̀n mítà 17.
Ní ìṣẹ́jú mẹ́jọ, Galatasaray gba àmì ayò kan wọlé láti ọwọ́ Y. Akgün pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ Leroy Sané, ṣùgbọ́n àwọn agbábọ́ọ̀lù Frankfurt dá padà pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta ní ààrin ìṣẹ́jú méjìlá pẹ̀lú àmì ayò kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ D. Sánchez, C. Uzun, àti J. Burkardt ní apá kìíní ìdíje náà.
Ní apá kejì, Galatasaray gbìyànjú láti gba ara wọn là, ṣùgbọ́n kò borí mọ́, Frankfurt ti sọ àmì ayò méjì mìíràn sínú àwọ̀n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ọwọ́ A. Knauff àti J. Burkardt, kí wọn tó sọ pé ó tó gẹ́.
Galatasaray pàdánù láti borí pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù wọn, ọmọ Nàìjíríà, Victor Osimhen, nítorí pé ó fara pa, kò sì gbá bọ́ọ̀lù fún wọn fún ìgbà díẹ̀ sí ibi tí a wà yìí.
Ìsubú Galatasaray òní ti gbé wọn lọ sí ìsàlẹ̀ tábìlì Champions League.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua


