Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Manchester City Gbó Ewúrò Sí Napoli Lẹ́nu Ní Papa Ìṣeré Etihad
Ní ọjọ́ kẹta ìdíje Champions League, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City gbó omi ewúrò sí ẹnu ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Napoli pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje náà, City àti Naples gbìyànjú gidigidi ní apá àkọ́kọ́ ìdíje náà, wọn kò fi góólù kan kùn-únlù fún ara wọn. Àwọn agbábọ́ọ̀lù City ṣe bí ẹni pé wọ́n jẹ́ olórí, wọ́n sì fi agbára hàn fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Napoli.
Ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àti àtamọ́tásẹ̀ tí ó gbóná janjan, Haaland, ni ó kọ́kọ́ sọ àmì ayò àkọ́kọ́ sínú àwọ̀n ní ìṣẹ́jú kẹrìndínlọ́gọ́ta lẹ́yìn tí ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Napoli kan tí ó ṣe àṣìṣe sì ti gba kaadi pupa ní ìṣẹ́jú kejìlélógún.
Jeremy Doku tún gba bọ́ọ̀lù kejì sínú àwọ̀n ní ìṣẹ́jú márùn-ún dínlọ́gọ́ta pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ T. Reijnders, ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù City mìíràn, èyí sì fún wọn láǹfààní láti gba ipò olúborí nínú ìdíje náà.
Kevin De Bruyne, ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí, náà tún fara hàn ní pápá ìṣeré náà lónìí lẹ́yìn tí ó kúrò ní ẹgbẹ́ náà kí sáà yìí tó bẹ̀rẹ̀. Ó sì gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú ayọ̀ ní Napoli lòdì sí ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀rí.
Ìṣẹ́gun òní gbe ẹgbẹ́ City lọ sí òkè lórí tábìlì ìdíje Champions League náà pẹ̀lú àwọn aṣẹ́gun mìíràn.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua


