Ẹṣin wá wọ Ògo Àdúgbò Chelsea FC láṣọ bí Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Brighton ṣe Pa Wọ́n Tì Ní Pápá Ìṣeré Wọn

Last Updated: September 27, 2025By Tags: , , , ,

Brighton sọ àruwọ orin Chelsea FC di ẹkún lọ́ọ̀sán gangan, wọ́n sì fi wọ́n ṣe ẹ̀lẹ́ya ní pápá ìṣeré Stamford Bridge, kò sì wá sí ọ̀rọ̀ lẹ́nu ògo àgbáyé mọ́.

Àmì ayò mẹ́ta sí ọ̀kan (3-1) ni wọ́n jẹ́ lónìí bí ìyà ti ṣe wá bá wọn múlẹ̀ bíi Ẹgbẹ̀ ìṣu, lẹ́yìn tí ọmọ ìkọ̀ wọn ní Trevoh Chalobah gba káàdì pupa ní ìṣẹ́jú mejileelaadotaì (52) lẹ́yìn tí ó kọlu àtàmatàṣe Brighton nígbà tí ó fẹ́ gbà bọ́ọ̀lù wọlé sílé wọn.

Enzo Fernández ló kọ́kọ́ sọ àmì ayò kan wọlé fún Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ní ìṣẹ́jú kẹrìnlélógún (24) pẹ̀lú orí àti ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Reece James, èyí ní tó jẹ́ akọni wọn tí wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ ní pápá ìṣeré náà.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n gba káàdì pupa ní ìpín kejì ìdíje náà tí ó sì dín àwọn agbábọ́ọ̀lù wọn kù sí mẹ́wàá lórí pápá, èyí ló fún Brighton ní àǹfààní láti ṣẹ́gun wọn bí ó ṣe ń se ojú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé akọni-mọ́ọ̀gbà Chelsea ṣe ìpáyà tí ó sì yọ àwọn agbábọ́ọ̀lù kọ̀ọ̀kan kúrò láti fi àwọn mìíràn rọ́pò, ó padà sọkún kíkorò ní ìgbẹ̀yìn ìdíje náà.

Dani Welbeck gba bọ́ọ̀lù méjì wọlé nígbà tí De Cuyper náà gba bọ́ọ̀lù kan wọlé fún Brighton tí wọ́n sì gba àmì ayò mẹ́ta tí ó yẹ lónìí.

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Chelsea wá di ẹni à ń fi se yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù mìíràn káàkiri àgbáyé lẹ́yìn tí wọ́n ti pàdánù àwọn ìdíje bíi mélòó kan sẹ́yìn báyìí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà bíi mẹ́wàá (10) ni ó wà ní àìlera tí wọn kò sì lè kópa nínú àwọn ìdíje wọn fún ìgbà púpọ̀ tí ó ń bọ̀ lọ́nà.

Wọn yóò koju ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Benfica nínú ìdíje Champions League ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, àmọ̀ kò sí ìdùnnú fún wọn nítorí pé akọni-mọ́ọ̀gbà tí ó wà níbẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó dára púpọ̀ tí ó ti bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.

Kíni ẹ rò pé yóò wá ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ní sáà yìí?

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment