Àwọn Ọlọ́ṣà Pa Ọkọ Ìyàwó, Wọ́n Sì Ji Ìyàwó àti Àwọn Meje Míìràn Gbé Ní Ìpínlẹ̀ Zamfara
Àwọn ọlọ́ṣà ti pa Mohammad Sani, ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, wọ́n sì ji ìyàwó rẹ̀ àti àwọn meje (7) mìíràn gbé ní Ìlú Maru, tí ó jẹ́ orílé-iṣẹ́ Ìjọba Ìbílẹ̀ Maru ní Ìpínlẹ̀ Zamfara.
Orísun kan tí ó kọ̀ láti dárúkọ rẹ̀ sọ fún TVC News pé, àwọn ọlọ́ṣà náà kọ lu Ìlú Maru ní àárọ̀ Ọjọ́ Ajé (Monday), wọ́n sì wọ ilé tọkọtaya tuntun náà pẹ̀lú èrò láti jí wọn gbé. Ṣùgbọ́n, ọkọ ìyàwó náà kọ̀ láti gbà fún wọn, èyí sì ló mú kí àwọn ọlọ́ṣà náà yìnbọn sí i lórí, wọ́n sì pa á.
Lára àwọn tí wọ́n jí gbé ni ọkùnrin mẹ́rin (4) àti obìnrin mẹ́ta (3), pẹ̀lú ìyàwó tuntun náà.
Orísun náà sọ pé: “Àwọn ọlọ́ṣà gbìyànjú láti jí ọkọ ìyàwó náà gbé, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti bá wọn lọ, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi yìnbọn sí i lórí, ó sì kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”
Ó fi kún un pé: “Mo ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń ní kó gun ọ̀kan lára àwọn mọ́tò àwọn ọlọ́ṣà náà, ṣùgbọ́n ó tẹnu mọ́ ọn pé òun kò ní bá àwọn ọlọ́ṣà náà lọ sí inú igbó.”
Ìjọba Ìbílẹ̀ Maru jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí ó ń ní ìrírí ìkọlù ọlọ́ṣà àti jíjí ènìyàn gbé fún owó ìràpadà.
Ìlú Maru tún ní àwọn ibi ìfarapamọ́ ọlọ́ṣà púpọ̀.
Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, nípasẹ̀ agbẹnusọ wọn, DSP Yazid Abubakar, sọ ní àkókò tí wọ́n ń kọ ìròyìn yìí pé òun kò mọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ó fi dá àwọn ènìyàn lójú pé wọ́n yóò tẹ̀síwájú nínú ìgbìyànjú láti gbógun ti ìwà-ọ̀daràn ní Zamfara.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

