Àwọn Ilé-Iṣẹ́ Epo àti Ilé-Ìwé Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ní Mali Láàrin Ìdínà Àwọn oníjàgídíjàgan
Àwọn ilé-iṣẹ́ epo kan ní olú ìlú Mali, Bamako, ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Ọjọ́ Ajé (Monday) fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí ẹgbẹ́ kan tí ó sún mọ́ al-Qaida ti fi ìdínà epo lé orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà náà, èyí wáyé nígbà tí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tí ó ru epo lọ́wọ́ ń gba orílẹ̀-èdè náà kọjá lábẹ́ ìlùfọ́.
Ilé-ìwé tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Bamako fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí àwọn jagunjagun JNIM ti bẹ̀rẹ̀ ìdínà náà ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn.
“Àwọn ọmọ náà lọ sí ilé-ìwé lónìí, ṣùgbọ́n àníyàn ṣì wà lọ́kàn mi,” Salif Traoré, òbí kan ní Bamako, sọ fún Associated Press. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ epo ṣì wà ní títìpa nítorí àìsí epo, mi ò sì mọ bóyá epo tí ó wà ní ìlú náà yóò pẹ́ tó.”
Wọ́n ti pa tánkà epo tó ju 100 run, tí àwọn ènìyàn púpọ̀ sì ti kú, tí wọ́n sì ti jí àwọn awakọ̀ gbé.
Ní Ọjọ́ Àìkú, Àjọ Ìṣọ̀kan Áfíríkà (African Union) kéde fún “ìgbésẹ̀ àgbáyé kánjúkánjú” láti dojú kọ ìpanilágbara ní Mali. Àtẹ̀jáde wọn tún dá lẹ́bi fún gbígbé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt mẹ́ta (3) tí wọ́n jí gbé níbẹ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, títí kan France àti U.S., ti gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn nímọ̀ràn láti kúrò ní Mali lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

