CANADA AIR

Air Canada Bẹrẹ si Fagile Àwọn ọkọ̀ òfuurufú Lórí Iyanṣẹ́lòdì Àwọn Olùṣèrànlọ́wọ́ nínú Òfuurufú

Last Updated: August 15, 2025By Tags: , ,

Ilé-iṣẹ́ Air Canada bẹ̀rẹ̀ sí fagilé àwọn oko òfuurufú rẹ̀ láti múra sílẹ̀ de iyanṣẹ́lòdì tí ó le waye lọ́wọ́ àwọn olùṣèrànlọ́wọ́ rẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú, èyí tí ó le da ìrìn-àjò duro fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èrò.

Ìdádúró pátápátá ti ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú tótóbi jù lọ ní Kánádà yóò kan àwọn èrò tí ó tó 130,000 lójoojumọ.

Gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà ti sọ, nípa ìfihàn lórí ìkànnì awùjọ X ti Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ tó 300 àwọn olùṣèrànlọ́wọ́ nínú ọkọ̀ òfuurufú ló kọ́ láti wá sí iṣẹ́ ní alẹ́ ọjọ́bọ̀, ìyẹn sì jẹ́ ìlọ́pò méjì nínú iye tí ó wọ́pọ̀.

CANADA AIR

CANADA AIR

Ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà kọ̀wé pé: “Èyí yóò fa àfikún ìfagilẹ́.”

Wọ́n tún fi kún un pé: “A banujẹ fún ainirorun ti iyanselodi yii le fa fún àwọn oníbàárà wa.”

Oludari iṣẹ ti Air Canada, Mark Nasr, sọ pé ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà ti bẹ̀rẹ̀ sí fi díẹ̀díẹ̀ dádúró àwọn iṣẹ́-ṣíṣe Air Canada ati Air Canada Rouge.

Nasr sọ pé àfojúsùn ètò yìí ni láti rí i dájú pé ìtúndè ìrìn-àjò yóò lọ láìsí ìṣòro, ati pé, lábẹ́ ipò tí ó dára, yóò gbà ọ̀sẹ̀ kan láti parí iṣẹ́ náà.

Ó sọ pé àwọn ìfagilẹ́ àkọ́kọ́ náà, tí ó kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ òfuurufú, yóò sábà kan àwọn òfuurufú ìrìn-àjò jíjìn sílẹ̀ ní òkèèrè tí wọ́n ṣètò láti lọ ni alẹ́ ọjọ́bọ̀.

Nasr tún sọ pé ìdádúró náà le mú kí àwọn ará Kánádà tí ó tó 25,000 wà ni òkèèrè láìní ọ̀nà láti padà lọ sí ilé wọn lójoojumọ.

 

editor's pick

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua