Sẹ́nátọ̀ Natasha Darapọ̀ Mọ́ Ìpolongo #JusticeForOchanya
Sẹ́nátọ̀ Natasha Akpoti-Uduaghan (PDP, Kogi Central) ti darapọ̀ mọ́ ìpè tuntun fún ìdájọ́ òdodo lórí ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13), Ochanya Ogbanje, ẹni tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́nà tí ó banújẹ́ ní ọdún 2018 lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n fi ń fura sí pé wọ́n ń ṣe ìfipábáni-lòpọ̀ fún.
Ìfipábáni-lòpò náà, tí wọ́n ròyìn pé ẹ̀gbọ́n bàbá Ochanya, Andrew Ogbuja, àti ọmọ rẹ̀, Victor, ṣe ní Ìpínlẹ̀ Benue, ru ìbínú orílẹ̀-èdè káàkiri, ó sì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn pè fún òfin tó le sí i láti dáàbò bo àwọn ọmọdé kúrò nínú gbogbo irú ìfipábani-lòpọ̀.
Nínú ìwé tí ó tẹ̀ jáde lórí ojú-ìwé Facebook rẹ̀ ní Ọjọ́bọ̀ (Thursday), Sẹ́nátọ̀ Akpoti-Uduaghan fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn pé àwọn tí wọ́n fura sí pé wọ́n ṣe ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣì wà ní òmìnira.
Ó sọ pé, “Ní ọdún méje (7) sẹ́yìn, ìtàn ọmọdé Ochanya fọ́ ọkàn mi. Mo rò pé àwọn tí ó ṣe ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lẹ́wọ̀n. Àbà, wọ́n tú wọn sílẹ̀, wọ́n sì dá wọn láre.”
Ó fìdí ìtìlẹ́yìn rẹ̀ múlẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo, ó sọ pé, “Nítorí àwọn ọmọ wa, mo dúró fún ìdájọ́ òdodo fún Ochanya,” nígbà tí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ajíjàgbara lórí ẹ̀rọ ayélujára, #miss_natural1, fún mímú ọ̀rọ̀ náà wá sí ìtẹ́tísí rẹ̀.
Ìpolongo #JusticeForOchanya ti tún gba agbára tuntun lórí ẹ̀rọ ayélujára, níbi tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń pè fún wíwádìí àti ìdájọ́ òdodo fún ọmọdébìnrin tí ó ti kú náà.
Sẹ́nátọ̀ Natasha rọ ìdílé Ochanya láti fi ẹ̀bẹ̀ àkọsílẹ̀ sílẹ̀ ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní Room 2:05, Senate Wing, National Assembly Complex, Abuja, ó sì ṣe ìlérí láti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ síwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua

