PSG Lé Chelsea Kúrò Nínú Ìdíje Champions League Pẹ̀lú Ìtìjú
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Paris Saint-Germain (PSG) ti na Chelsea FC bákàn bákàn pẹ̀lú àmì ayò mẹ́jọ sí méjì (8-2) nínú àpapọ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjèèjì nínú ìdíje Champions League tó ń lọ lọ́wọ́.
Chelsea, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé (Club World Cup), fìdí rẹmi pẹ̀lú ami ayò mẹ́ta sí òdo (0-3) ní pápá ìṣeré wọn ní Stamford Bridge, lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ pàdánù pẹ̀lú ami ayò márùn-ún sí méjì (5-2) lọ́dọ̀ PSG ní ìlú Paris ní ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn.
Iṣẹ́ ìyanu tí Chelsea ń retí láti yí àmì ayò padà di asán nígbà tí PSG gba àmì ayò méjì wọlé láàárín ìṣẹ́jú mẹ́rin-dín-lógún àkọ́kọ́ ní ìwọ̀-oòrùn London.
Àmì ayò kẹta tí PSG tún gbà wọlé ní ìdajì kejì jẹ́ kí àpapọ̀ àmì ayò tí Chelsea jẹ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjèèjì di mẹ́jọ, èyí sì ni iye àmì ayò tó pọ̀ jùlọ tí wọ́n máa jẹ nínú ìdíje Champions League rí.
Kò jẹ́ ìyanu pé àwọn olólùfẹ́ Chelsea bẹ̀rẹ̀ sí ní kígbe ẹgbin sí àwọn agbábọ́ọ̀lù wọn nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sinmi àti nígbà tí eré parí.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni inú àwọn olólùfẹ́ náà bà jẹ́ sí ọ̀gá ẹgbẹ́, Liam Rosenior, nígbà tí ó yọ Cole Palmer, Joao Pedro, àti Enzo Fernandez kúrò nínú eré ní ìdajì kejì.
Ìbànújẹ́ Chelsea tún pọ̀ sí i nígbà tí Trevoh Chalobah fara pa, tí wọ́n sì gbé e jáde lórí àkéte (stretcher), èyí tó mú kí Chelsea parí eré náà pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá nítorí pé wọ́n ti lo gbogbo àyè ìpàrọ̀ wọn tán.
Ọjọ́ náà kò rọ̀ rùn fún Rosenior rárá nítorí àṣìṣe láti ọ̀dọ̀ Mamadou Sarr, ẹni tí ó ṣeré ní ipò tí kì í ṣe tirẹ̀, jẹ́ kí Khvicha Kvaratskhelia gba àmì ayò àkọ́kọ́ wọlé ní ìṣẹ́jú kẹfà.
PSG tún gba àmì ayò kejì ní ìṣẹ́jú kẹrìn-dín-lógún nígbà tí Achraf Hakimi ran Bradley Barcola lọ́wọ́ láti gba bọ́ọ̀lù tó rẹwà wọlé.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù láti orílẹ̀-èdè Faransé yìí fi hàn pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti tún ife ẹ̀yẹ náà gbà padà. Inú bí àwọn olólùfẹ́ Chelsea sí i nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin Senny Mayulu gba àmì ayò kẹta wọlé ní ìṣẹ́jú méjì péré lẹ́yìn tí Rosenior ṣe ìpàrọ̀ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀.
Àmì ayò yìí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olólùfẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní kúrò ní pápá isere Stamford Bridge nítorí ìtìjú tó bá ẹgbẹ́ wọn.
Pẹ̀lú àṣeyọrí yìí, PSG ti kọjá sí ìpele mẹ́rin-dín-lógún (quarter-finals), níbi tí wọn yóò ti bá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool tàbí Galatasaray fẹsẹ̀wọnsẹ̀.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua





