EFCC Fi Ẹjọ́ Kan Ngige, Wọ́n Máa Pe Aṣáájú Mínísítà Náà Lójú Ẹjọ́ Ni Ọjọ́ Ẹtì

Last Updated: December 12, 2025By Tags: ,

Àjọ tí ó ń rí sí ìwà ìbàjẹ́ àti ètò ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè (EFCC) ti fi ẹ̀sùn mẹ́jọ (8) kan Chris Ngige, Mínísítà àná fún Iṣẹ́ Àgbẹ̀ṣẹ́ àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀.

Shola Soyele, oníròyìn àgbà Channels Television nípa ètò ìdájọ́, tí ó rí ẹ̀dà ẹ̀sùn náà, ròyìn pé wọ́n máa pe Mínísítà àná náà lójú Ẹjọ́ Gíga ti FCT ní Gwarimpa, Abuja, ni ọjọ́ Ẹtì.

Nínú ẹ̀sùn tí ó jẹ́ ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n (31st) Oṣù Kẹwàá tí Sylvanus Tahir, agbẹjọ́rò àgbà (SAN) àti àwọn agbẹjọ́rò márùn-ún (5) mìíràn fi sílẹ̀ fún EFCC, àjọ tí ń gbógun ti ìwà àjẹbánu sọ pé Ngige lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mínísítà àná láti fún àwọn alájọṣepọ̀ rẹ̀ àti àwọn ilé-iṣẹ́ oríṣiríṣi tí wọ́n gbà pé òun ni ó ni wọ́n ní ànfààní tí kò tọ́ nípa fífún wọn ní àwọn àdéhùn oríṣiríṣi.

Nínú ẹ̀sùn Kìíní (1), wọ́n fi ẹ̀sùn kan Mínísítà àná náà pé láàrin Oṣù Kẹ̀sán 2015 sí Oṣù Kàrún 2023, nígbà tí ó jẹ́ Mínísítà tó ń bójú tó Ilé-iṣẹ́ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ààbò Àwùjọ ti Nàìjíríà (NSITF), ó lo ipò rẹ̀ láti fún Cezimo Nigeria Limited ní ànfààní tí kò tọ́. Wọ́n gbà pé Ezebinwa Amarachukwu Charles, olùdarí àgbà/CEO ilé-iṣẹ́ náà, jẹ́ alájọṣepọ̀ rẹ̀.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó fún ilé-iṣẹ́ náà ní àwọn àdéhùn méje (7) oríṣiríṣi fún iṣẹ́ ìdámọ̀ràn, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìpèsè láti ọwọ́ NSITF, tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦366,470,920.68 (Ọ̀ọ́dúnrún-óle-Merindinlaadorin Mílíọ̀nù, irinwo-le-àádọ́rin ẹgbẹ̀rún,  ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti ogún náírà àti aadọ́ta-din-méjì Kobo, èyí sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó lòdì sí òfin, tí ó sì jẹ́ ìjìyà lábẹ́ abala 19 ti òfin Corrupt Practices and Other Related Offences Act, 2000.

Àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n mẹ́nu bá nínú ẹ̀sùn náà ni:

Zitacom Nigeria Limited: Ilé-iṣẹ́ tí Ezebinwa Amarachukwu Charles, olùdarí àgbà/CEO rẹ̀, gba àwọn àdéhùn mẹ́jọ (8) oríṣiríṣi fún ìpèsè, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdámọ̀ràn pẹ̀lú NSITF, tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦583,682,686.00 (Eedegbata Ati ogorin-o -le-meta Mílíọ̀nù, ẹgbẹta o le mejilelọgọri, ẹgbẹta o le merin-din-laadorun Naira).

Jeff & Xris Limited: Ilé-iṣẹ́ tí Nwosu Jideofor Chukwunwike, olùdarí àgbà/CEO rẹ̀, tún gba àwọn àdéhùn mẹ́jọ (8) oríṣiríṣi, tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦362,043,163.16 (Ọ̀ọ́dúnrún-ó-Ọdunrun o le mejilelọgọta Mílíọ̀nù, Egberun Mẹ́tàlelógójì Naira àti Kọ́bọ́ Mẹ́rindínlógun .

Olde English Consolidated Limited: Ilé-iṣẹ́ tí Uzoma Igbonwa, olùdarí àgbà/CEO rẹ̀, gba àwọn àdéhùn mẹ́rin (4) oríṣiríṣi fún ìdámọ̀ràn, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ ìkọ́lé láti ọwọ́ NSITF, tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦668,138,141.00 (Egbeta le mejidinlaadota Millionu, Egebrun lona ogorun le-mejidinlogoji ati ojilelogorunle okan naira ).

Shale Atlantic Intercontinental Services Limited: Ilé-iṣẹ́ tí Uzoma Igbonwa, olùdarí àgbà/CEO rẹ̀, tún gba àwọn àdéhùn mẹ́rin (4) oríṣiríṣi, tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦161,604,625.00 ogorunleniokanlelaadota milionu, egberun merin le legbeta ati egeba le ni arundinlohbon naira.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment