Mínísítà fún Ìdáàbòbò Orílẹ̀-èdè, Mohammed Badaru, Fi Ipò Sílẹ̀

Mínísítà fún Ìdáàbòbò Orílẹ̀-èdè, Mohammed Badaru, ti fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ìfipòsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Ààrẹ Tinubu, tí ọjọ́ kán Oṣù Kejìlá sì wà lórí rẹ̀.

Olùdámọ̀ràn Pàtàkì sí Ààrẹ lórí Ìsọfúnni àti Ìgbìmọ̀, Bayo Onanuga, lo fìdí èyí múlẹ̀ fún Channels Television ní Ọjọ́ Àìkú.

Agbẹnusọ ààrẹ náà sọ pé Abubakar fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ìlera.

Onanuga sọ pé Ààrẹ Tinubu tẹ́wọ́ gba ìfipòsílẹ̀ Abubakar, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà.

Gẹ́gẹ́ bí orísun ìròyìn láti Ààrẹ, ó ṣeéṣe kí Tinubu fi ẹni tí yóò rọ́pò Badaru ránṣẹ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láàárín ọ̀sẹ̀ yìí.

ÀTẸ̀JÁDE LÁTI ILÉ ÀÀRẸ

Badaru Abubakar, Mínísítà fún Ìdáàbòbò Orílẹ̀-èdè, Fi Ipò Sílẹ̀

Mínísítà fún Ìdáàbòbò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Alhaji Mohammed Badaru Abubakar, ti fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Nínú ìwé kan tí ọjọ́ kán Oṣù Kejìlá wà lórí rẹ̀, tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí Ààrẹ Bola Tinubu, Abubakar sọ pé òun fi ipò sílẹ̀ nítorí…

ó dájú pé nítorí ìlera gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni náà.

Abubakar, ẹni ọdún 63, jẹ́ Gómìnà sáà méjì ní Ìpínlẹ̀ Jigawa láti ọdún 2015 sí 2023.

Ààrẹ Tinubu ló yàn án sí ipò Mínísítà fún Ìdáàbòbò Orílẹ̀-èdè ní Ọjọ́ Kọkànlélógún Oṣù Kẹjọ, Ọdún 2023.

Ìfipòsílẹ̀ rẹ̀ wáyé láàárín ìgbà tí Ààrẹ Tinubu kéde pàjáwìrì ààbò orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ètò láti ṣàlàyé nípa rẹ̀ ní àkókò tí ó yẹ.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment