Àwọn Aṣojú (house-of-reps-

Àwọn Aṣojú Yóò Bẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Ní Ọjọ́rú, Oṣù Kọkànlá, 5

Last Updated: November 5, 2025By Tags: ,

Ilé Àwọn Aṣojú (House of Representatives) ti sọ pé àwọn yóò tún padà sí ìjókòó ní Ọjọ́rú, Oṣù Kọkànlá, ojo Karun-un, 2025.. Ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ìpinnu wọn láti dá ìpàdé dúró sí ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀.

Èyí wà nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Ilé Àwọn Aṣojú, Akin Rotimi Jnr fi síta.

Ó sọ pé ìpinnu náà tẹ̀lé àwọn ìdàgbàsókè rere tó wáyé láti inú àwọn ìgbésẹ̀ àti ìdásí káàkiri onírúurú ìpele ìjọba nípa àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìrúkèrúdò àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti àìtúsílẹ̀ owó lábẹ́ ìnáwó ọdún 2024/2025.

Ọ̀gbẹ́ni Rotimi sọ pé Akọ̀wé sí Ilé Àwọn Aṣojú, Yahaya Danzaria, fi àyípadà náà ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ nípasẹ̀ ìwé ìrántí inú ilé.

Ó sọ pé ìtúnpadà ní kùtùkùtù yóò fún àwọn olórí Ilé náà ní àǹfààní láti sọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ nípa ìlọsíwájú tí a kọ sílẹ̀ nínú yíyanjú àwọn ọ̀ràn àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jọ mọ́ orílẹ̀-èdè.

Ní ìpàdé ọjọ́rú, a retí pé Ilé náà yóò fagilé ìpinnu ìfàdúró rẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti jẹ́ kí ìgbésẹ̀ náà tẹ̀síwájú.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment