Chelsea Captain,Reece James, Marc Guiu, reuters.com,2025_newsml_UP1ELAI118761_441974145_768x432

Chelsea Lé Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Nottingham Forest Wọ Inu Igbó Aginjù

Last Updated: October 18, 2025By Tags: ,

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Chelsea ti fi ìbọn olóde lé ẹran Nottingham Forest wọ inú igbó àgìnjù lẹ́yìn tí wọ́n jẹ wọ́n àmì ayò mẹ́ta sí òdo ní pápá ìṣeré wọn ní City Ground.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ìkọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea kò sí lórí pápá láti bá wọ́n gbábọ́ọ̀lù nítorí àìlera kan tàbí òmíràn, Akọ́nilọ́gbọ́n Chelsea fi yé àwọn olólùfẹ́ Ẹgbẹ́ náà pé iṣẹ́ náà yẹ yékéyéké.

Ní saa àkọ́kọ́, àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjèèjì kọ́kọ́ tami ọ̀gẹ̀ sí ara wọn bí wọ́n kò ti lè gbà àmì ayò kankan sí inú àwọn fún ìṣẹ́jú márùndínlógójì (45) àti ìṣẹ́jú àfikún náà. Kódà, wọ́n gbìyànjú láti rí i pé àmì wọlé sí inú àwọn ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú wọn já sí òfo.

Akọ́nilọ́gbọ́n ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ṣe ìyọkúrò àti àfikún sí àwọn ọmọ ìkọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ bí ó ṣe yọ àwọn agbábọ́ọ̀lù iwájú rẹ̀ tí ó sì gbé àwọn mìíràn wọlé sí orí pápá. Kò pẹ́ sí ni Josh Acheampong kọ́kọ́ fi ìgùn orí gbà bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ wọlé sínú àwọn fún ẹgbẹ́ náà ní ìṣẹ́jú kọkàndínlaadota (49) pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ Pedro Neto.

Ní ìṣẹ́jú mẹ́ta sí i, ìyẹn ìṣẹ́jú méjìléláàádọ́ta (52) ni Pedro Neto gbà àmì ayò mìíràn wọlé láti ojú bọ́ọ̀lù ìwọn ọ̀fẹ́ (freekick) ní iwájú ilé àwọn Forest.

Àwọn Forest náà sa gbogbo ìpàá wọn àti agbára wọn láti rí i pé wọ́n da àmì ayò náà padà ṣùgbọ́n aṣọ kò bá ọmọ yé wọn mọ́, afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a sì ti rí ìdí àdìyẹ wọn.

Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ sí i, Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Chelsea gbà àmì kẹta wọlé sínú àwọn láti ọwọ́ ọ̀gágun ẹgbẹ́ náà, Reece James ní ìṣẹ́jú kẹrinlélógórin (84) pẹ̀lú bọ́ọ̀lù ara ńlá tí aṣóòlé Forest kò lè mú, tí ó fi àmì ayò náà ṣe mẹ́ta fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea tí wọ́n sì gba àmì mẹ́ta náà lónìí ní pápá ìṣeré City Ground.

Ní ìṣẹ́jú kẹtàdínlaadọ́rùn-ún (87), Malo Gusto gba káàdì pupa fún àṣìṣe tí ó ṣe tí ó sì gba ibẹ̀ jáde kúrò lórí pápá.

Ìròyìn ti gbó pé, àwuyáwuyá kan ti wà pé akọ́nilọ́gbọ́n Nottingham Forest ni, Ange Postecoglou ni wọ́n ti fún ní ìwé ìgbéléjẹ (sack letter) lẹ́yìn tí wọ́n rí ìjálulè ní ọwọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea lónìí.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment