Zelensky Múra láti Pàdé TRUMP Lẹ́hìn tí Kò sí Àgbàjọ nínú Ìjíròrò Amẹ́ríkà ati Russia
Àwọn ìjíròrò láàárín Ààrẹ Amẹ́ríkà Donald Trump àti Ààrẹ Russia, Vladimir Putin, parí láìsí àdéhùn lórí bí a se lè dá ogun ni Ukraine duro, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti n retí rẹ̀ bí àkókò ìyípadà.
Nígbà ìpàdé náà, Putin fi atilẹyin sí ọ̀rọ̀ Donald Trump pipẹ́ ni, ti ó sọ pé ìkọlù sí Ukraine kò ní wáyé bí ó bá jẹ́ òun ni ó wà ni ipò ìjọba.
https://www.africanews.com/embed/2823942
Putin sọ pé: “Lónìí, a gbọ́ Ààrẹ Trump sọ pé bí ó bá jẹ́ òun ni Ààrẹ, kò ní sí ogun. Mo ro pé ìyẹn yóò ti rí bẹ́ẹ̀. Mo jẹ́rii si.” “Èmi ati Trump ní ìbáṣepọ̀ tó lágbára, tó n ṣiṣẹ́, tó sì ni ìgbẹ́kẹ̀lé. Mo gbàgbọ́ pé a ṣì le dá ìjà yìí duro, àti pé bí a bá se yára dá a duro, bẹ́ẹ̀ ni yóò se dára tó.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àdéhùn tí a de, Trump fi ìrètí hàn nípa ọ̀nà tó wà níwájú.
Trump sọ pé: “Ìpàdé náà jẹ́ ìpàdé tó gbóná janjan. Ó jẹ́ ọkùnrin tó lágbára, ó sì le bi apaadi, ṣùgbọ́n ó gbóná láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pàtàkì méjì.
Mo ro pé a fẹ́rẹ̀ débẹ̀. Bayii, ó yẹ kí Ukraine fọwọ́sí rẹ̀. Ó le jẹ́ pé wọn yóò sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ nítorí pé Biden pín owó bíi sùwítì. A fúnni ní $350 bílíọ̀nù. Europe fúnni ní dín, ṣùgbọ́n ó pọ̀ síbẹ̀.”
Ìparí ọ̀rọ̀ náà ṣe Trump ní ìbànújẹ́, ẹni tí ó ti se ìlérí ní ìlọ́po láti dá ogun náà duro ni ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ó bá padà sí Ilé Aláwọ̀ funfun.
Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky, bá Trump sọ̀rọ̀ fún wákàtí tó ju kan lọ lẹ́hìn ìjíròrò àlàáfíà Alaska. A n retí pé yóò lọ sí Washington fún ìpàdé pẹ̀lú Trump ni ọjọ́ Àìkú bí ìjíròrò se n tẹ̀síwájú.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua