Tinubu Yan Ọmọ IBB Gẹ́gẹ́ Bí Alága Bank Of Agriculture

Ààrẹ Bola Tinubu ti yan Muhammad Babangida, ọmọ Ààrẹ ológun tẹ́lẹ̀, Ọ̀gágun Ibrahim Badamasi Babangida (tó ti fẹ̀yìn tì), gẹ́gẹ́ bí alága ti Bank of Agriculture (BOA) tí a tún ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan ní Ọjọ́ Jimọ̀ láti ọwọ́ agbẹnusọ ààrẹ, Bayo Onanuga, Ààrẹ Tinubu fọwọ́sí ìyàn yìí pẹ̀lú àwọn adarí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba apapọ̀ mẹ́jọ mìíràn.

Muhammad Babangida, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta (53), jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gbogboogbò Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti European University ní Montreux, Switzerland, níbi tí ó ti gba oyè Bachelor’s rẹ̀ nínú Business Administration àti oyè Master’s nínú Public Relations àti Business Communication.

Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Harvard Business School’s Executive Programme on Corporate Governance ní ọdún 2002.

Bákan náà, Ààrẹ Tinubu yan Lydia Kalat Musa láti Ìpínlẹ̀ Kaduna gẹ́gẹ́ bí Alága Oil and Gas Free Zone Authority (OGFZA); Jamilu Wada Aliyu láti Ìpínlẹ̀ Kano gẹ́gẹ́ bí Alága, National Educational Research and Development Council (NERDC); Hon. Yahuza Ado Inuwa, láti Ìpínlẹ̀ Kano bákan náà gẹ́gẹ́ bí alága Standard Organisation of Nigeria (SON) àti Sanusi Musa, SAN, (Ìpínlẹ̀ Kano) gẹ́gẹ́ bí Alága Institute of Peace and Conflict Resolution (IPCR).

Àwọn mìíràn pẹ̀lú: Professor Al-Mustapha Alhaji Aliyu láti Ìpínlẹ̀ Sokoto gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gíńráà Directorate of Technical Cooperation in Africa (DTCA) àti Sanusi Garba Rikiji láti Ìpínlẹ̀ Zamfara gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gíńráà Nigerian Office for Trade Negotiations (NOTN).

Àwọn yòókù pẹ̀lú Òní Tomi Somefun láti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí wọ́n yan gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Iṣẹ́ National Hydro-Electric Power Areas Development Commission (HYPPADEC) àti Dr. Abdulmumini Mohammed Aminu-Zaria láti Ìpínlẹ̀ Kaduna gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Àgbà Nigerian Integrated Water Resources Management Commission (NIWRMC).

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment