Super Falcons ti fi agbára wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tí ó gbà Ife-ẹ̀yẹ tó pọ̀ jùlọ ní Áfíríkà

Ẹgbẹ́ agbabọ́ọ̀lù obìnrin Nàìjíríà, Super Falcons, ti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo wọn fún ife-ẹ̀yẹ kẹwàá ti African Women’s Cup of Nations (WAFCON) pẹ̀lú ìṣẹ́gun tó gbópọn 3-0 lórí Tunisia.

Àwọn agbabọ́ọ̀lù náà ti wá ń pọkàn pọ̀ sí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn tó tẹ̀lé pẹ̀lú Botswana, tí wọ́n ti nireti lati gbà bọ́ọ̀lù pẹlu ni Ọjọ́rú, Oṣù Keje Ọjọ́ 8, 2025.

Super Falcon,

Omo egbe agbaboolu Nigeria se iranti agbaboolu Liverpool to ku laipe: @thenff.com

Nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n ṣe ní Casablanca ní Ọjọ́ Àìkú, Asisat Oshoala, tó jẹ́ agbabọ́ọ̀lù tó ti gbàwọn ife-ẹ̀yẹ lẹ́ẹ̀mẹfà ní Africa, ló gbá bọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ wọlé ní ìṣẹ́jú kẹrin.

Rinsola Babajide tún fi bọ́ọ̀lù wọlé fún Nàìjíríà ní ìparí ìwọ̀n àkọ́kọ́, ó sì gbá bọ́ọ̀lù kọjá gólí Tunisia fún àmì ayo kejì. Chinwendu Ihezuo, tí ó wá sí ipò, fi àmì ayo kẹta kún un ní ìṣẹ́jú kẹtàlélọ́gọ́rin láti fi àṣeyọrí wọn múlẹ̀.

Àwọn Super Falcons ti fi agbára wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tí ó gbà Ife-ẹ̀yẹ tó pọ̀ jùlọ ní Áfíríkà, wọ́n sì ń lépa Ife-ẹ̀yẹ WAFCON kẹwàá. Ìṣẹ́gun yìí ti fún wọn ní àmì mẹ́ta pàtàkì àti ìṣáájú ìgbà díẹ̀ ní ìpín B, ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mìíràn láàárín Algeria àti Botswana.

Botswana, tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìpele tí ó kéré jùlọ nínú ìpín náà, ń kópa nínú WAFCON fún ìgbà kejì péré, tí wọ́n sì kọ́kọ́ kópa ní ọdún 2022, nígbà tí wọ́n sì padà pàdé Super Falcons tí wọ́n sì pàdánù 2-0.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí ó wáyé ní Ọjọ́rú, Oṣù Keje Ọjọ́ 8, 2025, láàárín Nàìjíríà àti Botswana yóò jẹ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pàtàkì fún àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì ní ìpín B. Àwọn Super Falcons nírètí láti máa tẹ̀síwájú nínú ìṣẹ́gun wọn, nígbà tí Botswana yóò sì gbìyànjú láti fi ipa wọn hàn.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment