Spotify ti ṣe àtúnṣe Discover Weekly

Ní báyìí, ìwọ ni yóò yan ohun tí o fẹ́ gbọ́
Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Spotify ti jẹ́ kí kọnpútà yan orin fún wa, wọ́n ti yí ètò Discover Weekly padà. Ní báyìí, ìwọ fúnra rẹ ni yóò lè yan iru orin tí o fẹ́ gbọ́ lójoojúmọ́ Mọ́ńdè.
Àwọn tó ní Spotify Premium ni yóò lè lo àfihàn tuntun yìí. Nígbà tí o bá ṣí Discover Weekly rẹ sílẹ̀, Spotify yóò fi àwọn eré orin tó dá lórí ohun tí o ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ hàn lókè, gẹ́gẹ́ bí R&B, Afrobeats, Funk, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Tẹ eré tó bá yẹ ẹ, akojọ orin rẹ yóò yí padà lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ kí o le gbọ́ ohun tó bá mọ́ o nínu.
Spotify sọ pé:
“Bóyá o fẹ́ gbọ́ ohun tí o ti mọ́ tẹ́lẹ̀ tàbí o fẹ́ ṣàyè wá tuntun, Discover Weekly yóò mú ohun tí o fẹ́ wá fún ọ.”
Àtúnṣe yìí fi hàn pé Spotify fẹ́ kí ìwọ fúnra rẹ ní àṣẹ lori ohun tí o gbọ́, kó má jẹ́ pé kọnpútà ní láti yan fún ọ nìkan.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua