PA MEDIA, Christaian Horner

Red Bull Ti Le Oga Agba Ẹgbẹ Horner Kúrò Ní Iṣẹ́

Last Updated: July 9, 2025By Tags: , , ,

Red Bull ti lé Christian Horner kúrò nínú iṣẹ́ lẹ́yìn ogún ọdún ogún ọdún tí ó ti jẹ́ olùdarí ẹgbẹ́.

Ọmọ ọdún mọ́kànléláàdọ́ta [51] yìí ti jẹ́ olórí ẹgbẹ́ Formula 1 náà láti ìgbà tí wọ́n ti dá a sílẹ̀ ní ọdún 2005.

Láti ìgbà náà, Red Bull ti gba ife ẹ̀yẹ ninu ìdíje awakọ̀, [drivers’ championship] ní ẹ̀ẹ̀mẹjọ [8], pẹ̀lú Max Verstappen tó ti gba ife ẹ̀yẹ mẹ́rin tí ó kẹ́yìn.

Ìgbésẹ̀ yìí wá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí agbára ẹgbẹ́ náà ti ń lọ sílẹ̀ àti àríyànjiyàn nínú ilé-iṣẹ́ ní ipò gíga jù lọ, àti oṣù mẹ́tàdínlógún [17] lẹ́yìn tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfìyà-jẹni-lórí-ìbálòpọ̀ [sexual harassment] àti ìwà ìfipá-múni-ṣe-ohun-tí-a-kò-fẹ́ [coercive, controlling behaviour] kan Horner láti ọ̀dọ̀ obìnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́.

Wọ́n ti yọ Horner lẹ́bi ní ẹ̀ẹ̀méjì [2] lórí àwọn ẹ̀sùn náà láti ọwọ́ ilé-iṣẹ́ òbí ẹgbẹ́ náà, Red Bull GmBH.

“Red Bull ti ro Christian Horner loye kúrò nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ láti òní, wọ́n sì ti yan Laurent Mekies gẹ́gẹ́ bíi Aláṣẹ Àgbà [CEO] ti Red Bull Racing,” ni Red Bull GmbH sọ nínú àtẹ̀jáde kan ní Ọjọ́rú.

Lábẹ́ Horner, Red Bull ti gba àṣeyọrí nínú ìdíje àwọn ọ̀mọ̀lé [constructors’ championship] ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà [6], pẹ̀lú Sebastian Vettel tó gba ìdíje awakọ̀ láti ọdún 2020 sí 2013.

Oliver Mintzlaff, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ Red Bull tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé-iṣẹ́ àti àwọn ìnáwó, fi kún un pé: “A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christian Horner fún iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tó ti ṣe láti ogún ọdún sẹ́yìn”

“Pẹ̀lú ìfaramọ́ rẹ̀ láìsimi, ìrírí, ìmọ̀ àti ìrònú tuntun, ó ti kó ipa pàtàkì nínú dídá Red Bull Racing sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ tí ó jáwé olúborí jù lọ àti tí ó wuni jù lọ nínú Formula 1.

“O ṣeun fún gbogbo nǹkan tó o ṣe, Christian, wàá sì máa wà lára àwọn tó ṣe pàtàkì nínú ìtàn ẹgbẹ́ wa títí láé

Iṣẹ́ tí wọ́n yọ Horner lẹ́nu bọ̀ láàrín àìdánilójú nípa ọjọ́ ọ̀la Verstappen tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ tó gbajúmọ̀ jùlọ.

Ẹni tó ti gba àkọlé ayé mẹ́rin [4] yìí wà lábẹ́ ìwé àdéhùn pẹ̀lú Red Bull títí di ọdún 2028, ṣùgbọ́n Mercedes ń halẹ̀ mọ́ ọn láti lè darapọ̀ mọ́ wọn fún àkókò tí ó ń bọ̀.

Red Bull ti gba ìdíje méjì péré ní àkókò yìí gẹ́gẹ́ bí McLaren ti gbapò wọn gẹ́gẹ́ bíi ẹgbẹ́ tí ó yẹ fún ìfagbára.

Ìdínkù wọn bẹ̀rẹ̀ ní àárín àkókò tí ó kọjá; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Verstappen gba àkọlé ayé kẹrin [4] rẹ̀ ní tààrà, ó gba ìdíje méjì péré nínú àwọn ìdíje mẹ́rìnlá [14] tí ó kẹ́yìn.

Orisun: BBCNEWS

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment