PSG kò káàánú Marid, wọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe máa ń ṣe ojú
Nínú ìdíje FIFA CLUB WORLD CUP tí ó ń lọ lọ́wọ́, ìpele àṣekagba, Paris Saint-Germain fi Real Madrid ṣe ẹlẹ́yà pẹ̀lú àmi ayò mẹ́rin sí òdo.
Olùdíje ikọ̀ ilẹ̀ Faransé àti aṣégbá ilẹ̀ Yúróòpù fi ẹ̀kọ́ wọn hàn fún Madrid ní pápá ìṣeré MetLife ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù keje ọdún 2025 nínú ìdíje
Wọ́n gba bọ́ọ̀lù jù ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà, èyí sì mú kí èsì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà gbé wọn dé ipò tó yẹ láti wọ inú ìdíje àṣekágbá ní ọjọ́ Àìkú.
Fabian Ruiz ló gba àmi ayò àkọ́kọ́ wọlé ní ìṣẹ́jú kẹfà nígbà tí Ousmane Dembele gba àmi ayò kejì wọlé ní ìṣẹ́jú mẹ́ta sí ìgbà náà, èyí tí ó mú kí ó da góòlù méjì fún Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Faransé.
Ní ìṣẹ́jú kẹrìnlélógún, ììrànwọ́ tó tayọ láti ọwọ́ Hakimi fún Ruiz láǹfààní mìíràn láti gba àmi ayò kẹta wọlé fún wọn ní ìdajì àkọ́kọ́ nínú ìdíje bọ́ọ̀lù.
Oju ojọ́ náà dúdú fún ẹgbẹ́ Madrid àti àwọn olólùfẹ́ wọn nítorí PSG kò kò ṣe dáwọ́ dúró lẹ́yìn góòlù mẹ́ta.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ Madrid gbìyànjú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọn kò lè gba àmi ayò kankan wọlé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Ní ìṣẹ́jú kẹtàdínláàádọ́rùn-ún, B. Barcola fún Goncalo Ramos ní àyè gbígbámúṣé láti fi àmi ayò kẹrin di èsì náà.
Ìṣẹ́gun tí wọ́n ṣe lónìí yìí ti fún PSG ní àyè nínú ìdíje tí wọ́n máa bá Chelsea tí ó jẹ́ aṣẹ́gun nínú ìdíje UEFA Conference League, gbaní ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje ọdún 2025 ní America.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua