PSG Dé Ìpele Àwọn Mẹ́rin Tó Kẹ́yìn Nínú FIFA Club World Cup Pẹ̀lú Àwọn Agbábọ́ọ̀lù Mẹ́sàn-án

Paris Saint-Germain (PSG) ti wọ ìpele àwọn mẹ́rin tó kẹ́yìn nínú FIFA Club World Cup lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun Bayern Munich pẹ̀lú àmi ayò 2-0 nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ alárinrin kan, bó ti wù kí wọ́n fi àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́sàn-án parí eré náà lórí pápá. Ìjàkadì tó gbóná yìí wáyé ní Atlanta, ó sì fi PSG sípò tó dára láti gbégbá orókè mìíràn.

Ìlàkàkà àkọ́kọ́ eré náà kò sí àmì ayò, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì tí wọ́n gbìyànjú láti gba bọ́ọ̀lù wọlé. Àmọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani nínú jẹ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí agbábọ́ọ̀lù Bayern, Jamal Musiala, fara pa nípa burúkú lẹ́yìn tí ó kọlu eni ti o so ile PSG, Gianluigi Donnarumma. Ìpalára náà mú kí wọ́n mú Musiala kúrò ní ori pápá, ó sì yí ipò eré náà padà.

Jamal Musiala, Bayern Munich

Wọ́n rí Jamal Musiala, agbábọ́ọ̀lù Bayern Munich, ní ìrora lẹ́yìn tí Gianluigi Donnarumma, agbábọ́ọ̀lù PSG, gbé e bolẹ̀.
Àwòrán: Getty Images

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà gbóná, Desire Doue ló gbà bọ́ọ̀lù wọlé àkọ́kọ́ fún PSG ní ìṣẹ́jú kejidínlọ́gọ́rin (78th minute) lẹ́yìn tí João Neves gbà bọ́ọ̀lù lọ́wọ́ Harry Kane. Àmì ayò yìí fún PSG ní ànfàní, ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ipò eré náà di rírú.

PSG wá di agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá nígbà tí Willian Pacho gba káàdì pupa kan fún ìwà tí kò bójú mu. Pẹ̀lú ipò àìmúnáradà yìí, Bayern Munich gbìyànjú láti fi gbogbo agbára kọlu, wọ́n sì rò pé wọ́n ti gbà bọ́ọ̀lù wọlé kan nípasẹ̀ Kane, ṣùgbọ́n wọ́n fagi lé e nítorí offside.

Lóde ìparí eré náà, ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ṣẹlẹ̀ nígbà tí Lucas Hernandez, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù PSG, gba káàdì pupa mìíràn fún fífìí fi igun ọwọ́ lu Raphaël Guerreiro. Èyí fi PSG sípò tí wọ́n ní agbábọ́ọ̀lù mẹ́sàn-án péré lórí pápá.

Bí ó ti wù kí ó rí bẹ́ẹ̀, Ousmane Dembele, tí ó wá síbẹ̀ bí agbábọ́ọ̀lù àyípadà, fi ìrètí Bayern dopin nígbà tó gbá bọ́ọ̀lù wọlé kejì fún PSG ní ìṣẹ́jú kẹfà àfikún (90+6), lẹ́yìn tí Achraf Hakimi ṣe iṣẹ́ tó dára gan-an. Bayern tún gbìyànjú láti gba ìfìyàjẹ kan ní ìparí, ṣùgbọ́n VAR yí ìpinnu adájọ́ padà lẹ́yìn àyẹ̀wò.

PSG vs Bayern

Ousmane Dembele àti Achraf Hakimi Ní Ayẹyẹ Lẹ́yìn Ti Dembele Gbá Bọ́ọ̀lù Kejì PSG Wọlé [Kai Pfaffenbach/Reuters

Pẹ̀lú ìṣẹ́gun yìí, PSG ti dé ìpele Club World Cup semi-final, níbi tí wọ́n yóò ti dojú kọ Real Madrid

Orisun: Iroyin.ng

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment