Òtítọ́ ni pé Buhari ti ń ṣàìsàn – Bashir Ahmad
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Muhammadu Buhari, ti ṣàìlera, wọ́n sì ti gbé e lọ sí iléewòsàn ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ.
Olùrànlọ́wọ́ fún Ààrẹ nídìí ìròyìn, Bahri Ahmad sọ nínú àtẹ̀jíṣẹ́ rẹ̀ ní X ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kẹ́rin osù kẹ́je ọ́dun 2025
“Lórí àwọn ìròyìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nínú àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn pé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Muhammadu Buhari ti ń ṣàìsàn tó le gan-an, tí wọ́n sì ti gbà á sí Ìtọ́jú Àkànṣe (ICU), a rí i pé ó pọn dandan láti sọ ohun tí ó wà nílẹ̀.”
Ó tẹ̀síwájú pé:
“Ó jẹ́ òtítọ́ pé Ààrẹ Buhari tẹ́lẹ̀ kò ní ìlera tó dáa, ó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ àwọn oníṣègùn. Ṣùgbọ́n, kó dájú pé àwọn ìròyìn tó ń tan pé àìlera rẹ̀ burú gan-an ti pọ̀ ju, ó dúró sán-ún, ó sì ń dáhùn dáadáa sí ìtọ́jú, a sì nírètí pé ara rẹ̀ yóò yá pátápátá.
Ó tún fi kún un pé:
“A dúpẹ́ fún àdúrà àti ìfẹ́ rere tí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ àti àwọn olùfẹ́ rẹ̀ jákèjádò ayé ń fún un. A tẹsiwaju lati gbadura fun imularada pipe ati iyara rẹ”.
Ẹ ṣeun!
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua