Orílẹ̀-èdè Ghana Bẹ̀rẹ̀ Ìwádìí Nípa Jàm̀bá Ọkọ̀ Òfurufú Tí Ó Pa Mínísítà Méjì
Ààrẹ John Mahama kéde ní ọjọ́bọ̀ pé ìjọba Ghana ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kíkún nípa ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú tí ó pa àwọn mínísítà mẹ́ta, ìyẹn mínísítà fún ààbò, àti mínísítà fún àyíká, àti àwọn ènìyàn mẹ́fà mìíràn.
Mínísítà fún ààbò, Edward Omane Boamah, Mínísítà fún àyíká, Ibrahim Murtala Muhammed, àti àwọn ènìyàn mẹ́fà mìíràn, títí kan àwọn olóṣèlú gíga àti àwọn òṣìṣẹ́ agbógunti ọkọ̀ òfurufú, ni wọ́n kú nínú ìjàm̀bá náà ní ọjọ́rú.
Mahama sọ nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó fi sáfẹ́fẹ́ pé, “Àwọn ọmọ ogun Ghana ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kíkún àti òtítọ́ nípa àwọn ohun tí ó yí ìjàm̀bá yìí ká.”
Ó sọ pé wọ́n ti rí àwọn ìwé-aṣẹ́ ìṣàkóso ìṣe ọkọ̀ òfurufú àti ohùn ìgbàsílẹ̀ nínú ọkọ̀ òfurufú, wọ́n sì ti dá “ìgbìmọ̀ ìwádìí pàtàkì kan sílẹ̀ láti wádìí ìdí ìjàm̀bá náà.”
Ọkọ̀ òfurufú onítẹ́ẹ́rẹ́ náà kò farahàn mọ́ lórí ẹ̀rọ àwárí ọkọ̀ òfurufú ní kété lẹ́yìn tí ó kúrò ní Accra ó sì ń lọ sí Obuasi ní gúúsù Ghana.
Mahama sọ pé, a ti rí gbogbo òkú mẹ́jọ náà, ìsìnkú ìjọba yóò sì wáyé ní oṣù kẹjọ, ọjọ́ kẹẹ̀dógún.
Ààrẹ náà fi kún un pé, “A ti pàdánù díẹ̀ lára àwọn amọ̀dájú orílẹ̀-èdè wa ní àkókò kan tí gbogbo wa ní ìbànújẹ́.”
Mahama ti dá gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ dúró fún ìparí ọ̀sẹ̀, ó sì ti kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìbànújẹ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́bọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn asia tí a gbọ́dọ̀ gbé sí ìdajì ibi tí wọ́n máa ń gbè sí.
Oríṣun, AFP/ Channels
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua