America, Nigerian embassy.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dín ìgbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń gba ìwé ìrìnnà kù

Last Updated: July 9, 2025By Tags: , , , ,

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dín ìtẹ́wọ́gbà àṣẹ àbẹwò fún àwọn arìnrìn-àjò Nàìjíríà kù

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti kéde àwọn ìyípadà gbòǹgbò nínú ètò ìwé àṣẹ ìrìn-àjò tí kìí ṣe ti ìgbé-ìgbélẹ̀ (non-immigrant visa) fún Nàìjíríà, wọ́n ti dín àkókò àti ipò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arìnrìn-àjò Nàìjíríà lè wọ orílẹ̀-èdè náà kù.

Bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ oṣù keje, Ẹ̀ka Ìjọba Amẹ́ríkà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè (US Department of State) sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ìwé àṣẹ ìrìn-àjò tí kìí ṣe ti ìgbé-ìgbélẹ̀ àti tí kìí ṣe ti òṣìṣẹ́ ìjọba orílẹ̀-èdè (non-immigrant and non-diplomatic visas) tí wọ́n fún àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò jẹ́ ìwọlé ẹyọ kan ṣoṣo, yóò sì wúlò fún oṣù mẹ́ta péré.

Wọ́n sọ pé èyí jẹ́ apá kan nínú ìtúnṣe àṣẹ àbẹwò àgbáyé, ìyípadà tó lágbára láti inú àwọn ìlànà àṣẹ àbẹwò tẹ́lẹ̀, tí ó máa jẹ́ kí wọ́n lè wọ orílẹ̀-èdè ní ọ̀pọ̀ ìgbà fún ọdún méjì tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ.

Nàìjíríà tún ń fúnni ní àwọn àṣẹ àbẹwò ìwọ̀lé kan ṣoṣo tó wúlò fún oṣù mẹ́ta nìkan fún àwọn tí ń gbero láti ṣàbẹwò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti Nàìjíríà.

Ìjọba Nàìjíríà kò tíì sọ ìdáhùn kankan.

Ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ sọ wípé àwọn ìlànà lórí ìwé-àṣẹ ìrìnnà wà “ní ìkáwọ́ àtúnyẹ̀wò tí ó ń lọ lọ́wọ́” ó sì lè yí padà ní ìbámu pẹ̀lú ìyípadà àwọn ìlànà àjùmọ̀sọ̀rọ̀, ààbò, àti àwọn ìlànà àtìpó.

Nínú àtẹ̀jáde kan, ìjọba Amẹ́ríkà sọ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ Nàìjíríà láti ríi dájú pé orílẹ̀-èdè náà bá àwọn ìlànà àgbáyé pàtàkì mu.

Àwọn ìlànà wọ̀nyí ni:

  • Yíyan àwọn ìwé ìrìn-àjò tí ó ní ààbò.
  • Ṣíṣàkóso àwọn tí ó ju àkókò ìwé àṣẹ ìrìn-àjò wọn lọ (visa overstays).
  • Pínpín àwọn ìdàpọ̀ ààbò tàbí ìdàpọ̀ ìwà ọ̀daràn fún àwọn ète ààbò gbogbo gbò.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tún pàṣẹ pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn àkọọ́lẹ̀ orí ayélujára ti gbogbo àwọn àjèjì tí wọ́n ń béèrè fún ìwé àṣẹ ìrìnnà, títí kan àwọn ọmọ Nàìjíríà, fún “ohun tó bá fi hàn pé wọ́n kórìíra àwọn aráàlú, àṣà, ìjọba, àwọn ilé-iṣẹ́, tàbí àwọn ìlànà tí wọ́n fi dá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sílẹ̀”

Àwọn ọmọ Nàìjíríà wà lára àwọn tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn tó ń tọrọ ìwé àṣẹ ìrìnàjò-àjò-ẹ̀kọ́ sí Amẹ́ríkà lágbàáyé..

Orisun: BBCNEWS

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment