Orí Ló Yọ Ìparun Kúrò Lójú Chelsea Lónìí Lọ́wọ́ Crystal Palace

Last Updated: August 17, 2025By Tags: , ,

Chelsea FC àti Crystal Palace gba ami ayò òdo sí òdo lónìí ní pápá Stamford Bridge, nínú ìdíje àkọ́kọ́ ti Premier League fún àkókò tuntun.

Lẹ́yìn tí Chelsea ti gba Ifẹ-ẹ̀yẹ àgbáyé fún àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Club World Cup tí wọ́n sì gba bọ́ọ̀lù tó dára nínú àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ṣáájú ìgbà àkókò tuntun àti ìgbà tí wọ́n gbé àwọn agbábọ́ọ̀lù tuntun wọlé, wọ́n kùnà láti borí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ wọn ní ilé. Ìyẹn náà lórí ẹni tí ó gba FA Cup àti Community Shield Cup.

Joao Pedro

Agbábọ́ọ̀lù Crystal Palace, Eze, gba bọ́ọ̀lù kan tí ó rẹwà wọlé, ṣùgbọ́n wọ́n fagilé rẹ̀ lẹ́yìn tí VAR ti yẹ góòlù náà wò.

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Palace gba bọ́ọ̀lù tó rẹwà, wọ́n dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dúró, wọ́n sì gbèjà ilé wọn láti má jẹ́ kí wọ́n gbà wọ́n ní góòlù.

Olùkọ́ni Chelsea bínú gan-an ní ìdajì kejì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ nígbà tí Andrew Santos fi àǹfààní kan tí ó hàn gbangba ṣòfò, ó sì gba bọ́ọ̀lù náà kọjá orí àwọ̀n dípò kí ó gbé Chelsea wá sí iwájú lórí Palace.

Àwọn Blue gbìyànjú gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, ṣùgbọ́n Crystal Palace fi hàn wọ́n pé àwọn kò wá síbẹ̀ láti ṣeré lásán.


Tẹ̀lé wa fún ìròyìn mìíràn lórí àtẹ̀gùn wa.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment