Orí ló kó ògo àdúgbò (Manchester United) yọ lọ́wọ́ Fulham lónìí, ikú ìbá pa wọ́n.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United FC kò lè ṣẹ́gun lónìí lodo Fulham ní Craven Cottage bí wọ́n ṣe gbá bọ́ọ̀lù dọ́gba pelu ami ayo 1-1.
Goòlù ara-ẹni Rodrigo Muniz, tí ó yípadà láti orí Yoro, fún àwọn Red Devils ní ààyè àkọ́kọ́ ní ìdajì kejì. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Bruno Fernandes ṣaláìwọlé àmì ìyà jẹ́ tí ó gbópọn gidigidi tí adájọ́ fún wọn lẹ́yìn tí Calvin Bassey ṣe àṣìṣe ìwà àfojúdi sí Mason Mount nínú agbègbè ẹ̀gbẹ́ olùṣọ́.
Ìbànújẹ́ pọ̀ sí i ní ojú àwọn olólùfẹ́ United nínú papa ìṣeré lẹ́yìn àmì ìyà jẹ́ tí olórí ẹgbẹ́ náà ṣaláìwọlé boolu ninu yara oluso, èyí tí ó dàbí ẹni pé ó mú wọn bínú gidigidi.
Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú ti àwọn agbábọ́ọ̀lù Manchester United ti gba danu, Emile Smith mú èlé náà dọ́gba pẹ̀lú ìkọlù ńlá kan nínú àlàfo, èyí tí agbábọ́ọ̀lù náà kò lè mú.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùkọ́ àgbà Ruben Amorim mú atamatase tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wọlé, Benjamin Šeško, wá láti ran ẹgbẹ́ náà lọ́wọ́, wọn kò lè gba ìṣẹ́gun.
United kò ní ìṣẹ́gun nínú ìdíje méjì àkọ́kọ́ tí wọ́n kópa nínú ìdíje Premier League lẹ́yìn tí Arsenal lù wọ́n ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, tí wọn kò sì lè di ipò iwájú wọn mú ní Craven Cottage, pẹ̀lú ìfúnpá tó ti ń kó sí Ruben Amorim tó jẹ́ olùkọ́ àgbà
Ẹgbẹ́ Ruben Amorim fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé wọ́n ṣaláìgba àmì ìdọ́gba ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje lòdì sí Arsenal, wọ́n fi 1-0 tẹ́pa lẹ́yìn tí àṣìṣe gbàsìn Altay Bayindir jẹ́ kí Riccardo Calafiori fi orí gbà wọlé.
Benjamin Sesko yóò ní láti dúró de ìfihàn rẹ̀ ní kíkún fún United, lẹ́yìn tí orúkọ rẹ̀ ti wà lára àwọn tí ó jókòó ní Fulham.
Amorim ṣe ìyípadà kan ṣoṣo láti ẹgbẹ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ ìdíje lòdì sí Arsenal, pẹ̀lú Amad tí ó wọlé sí ipò alábọ́lùwé apá ọ̀tún àti Diogo Dalot tí ó jókòó sí orí pákó àwọn tí ó wà lẹ́yìn.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua