Ọlọ́ọ̀pàá Mú Àwọn Èèyàn Méjì Lórí Ìpànìyàn Ọmọ Ọdún 5 Ní Enugu

Ọlọ́ọ̀pàá Mú Àwọn Èèyàn Méjì Lórí Ìpànìyàn Ọmọ Ọdún 5 Ní Enugu

Last Updated: August 20, 2025By Tags: , ,

Àjọ Àwọn Ọlọ́ọ̀pàá Ìpínlẹ̀ Enugu ti mú afurasi kan, Ikediekpere Obodoagu, lórí ẹ̀sùn íjìgbé àti ìpànìyàn Wisdom Oboagu, ọmọ ọdún márùn-ún tí ó jẹ́ ìbátan rẹ̀.

Èyí wà nínú atejade kan láti ọwọ́ olùdarí ọ̀rọ̀ àwùjọ ti àjọ náà, SP DANIEL NDUKWE, tó sọ pé àwọn ọlọ́ọ̀pàá tún ti mú Sunday Michael, ẹni tí ó ṣìṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí í ṣe ẹ̀ṣọ́ ní 9th Mile àti ọmọ ìlú Mayo-Belwa ní ìjọba ìbílẹ̀ ti Ìpínlẹ̀ Adamawa.

Àjọ náà ṣàlàyé pé Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọlọ́ọ̀pàá tí ń Dènà Jíjígbé Ènìyàn ló mú àwọn olùfura náà, lẹ́yìn ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ròyìn ìbéèrè fún owó ìdásílẹ̀.

Ọlọ́ọ̀pàá Mú Àwọn Èèyàn Méjì Lórí Ìpànìyàn Ọmọ Ọdún 5 Ní Enugu

Ọlọ́ọ̀pàá Mú Àwọn Èèyàn Méjì Lórí Ìpànìyàn Ọmọ Ọdún 5 Ní Enugu – TVC

Ó sọ pé wọ́n kọ́kọ́ ròyìn pé ọmọ náà ti sọ nù ní 26 Oṣù Keje ọdún 2025, lẹ́yìn ìwádìí tí àwọn ọlọ́ọ̀pàá ṣe, tí wọ́n sì ṣàwárí pé olùfura àkọ́kọ́ náà lo ẹni tí ó ṣìṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti béèrè fún owó ₦1,000,000 lọ́wọ́ bàbá ọmọ náà, láti fi ara rẹ̀ pamọ́.

Nígbà tí wọ́n kò san owó ìdásílẹ̀ náà, olùfura náà pa ọmọ náà, ó sì sin ín sínú igbó kan nítòsí ibùgbé wọn ní Okinitor, Amankwo Ngwo, Ìjọba Ìbílẹ̀ Udi.

Gbólóhùn náà sọ pé olùfura àkọ́kọ́ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, ó sì tọ́ àwọn ọlọ́ọ̀pàá lọ sí ibi tí wọ́n ti wá òkú náà jáde níwájú àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn, tí dókítà wà lára wọn, tí ó sì jẹ́rìí sí i pé ọmọ náà ti kú.

Kọmiṣọ́nà Àwọn Ọlọ́ọ̀pàá, CP Mamman Bitrus-Giwa, fi ìdí ìpinnu Àjọ náà múlẹ̀ láti tẹnu mọ́ ìwádìí lórí àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó burú, ó sì fi dá àwọn ènìyàn lójú pé a óò fi àwọn olùfura náà lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìwádìí.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment