Dr-Fortune-Gomo, Zimbabwe, UK

Okunrin kan pa Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Zimbabwe ní UK

Last Updated: July 7, 2025By Tags: , , ,

Ìdílé onímọ̀ sáyẹ́sì ọmọ orílẹ̀-èdè Zimbabwe kan wà nínú ìdààmú ńlá lẹ́yìn tí wọ́n pa á

Obìnrin náà, Dr. Fortune Gomo, tó jẹ́ ọmọ okandinlogoji ọdún (39-year-old), kú lẹ́yìn tí ó fara pa ní ojú pópó kan ní agbègbè Lochee ní ìlú Dundee ní ọ̀sán Ọjọ́ Satide.

Dr-Fortune-Gomo, Lochee, UK, Dundee

Dr-Fortune-Gomo-Completed-her-PhD 2002- Police Scotland

Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún ti fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó pa onímọ̀ sáyẹ́sì kan tí wọ́n rí ní òpópónà kan nílùú Dundee.

Dókítà Fortune Gomo, ẹni ọdún mokandínlógójì, ni àwọn oníṣẹ́-ìtọ́jú pàjáwìrì tọ́jú ṣùgbọ́n ó kú ní South Road, ní agbègbè ìlú Lochee ní ọ̀sán ọjọ́ Sátidé.

Kyler Rattray, láti ìlú Dundee, kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì rán an lọ sí àtìmọ́lé nígbà tó fara hàn ní ìkọ̀kọ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Sheriff ti ìlú Dundee.

Fortune, tí ó jẹ́ ọmọ ìlú Mutare ní ìlà-oòrùn Zimbabwe, ti gba oyè PhD ní Yunifásítì Dundee, ó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ fún Scottish Water.
Ìdílé Dókítà Gomo ní Zimbabwe sọ fún BBC News pé ìyàlẹ́nu gbáà ni ìròyìn ikú rẹ̀ ṣì jẹ́ fún wọn.

Arakunrin rẹ̀ Regis Nyatsanza sọ pé ó máa pé ogójì ọdún ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan sí i, àti pé láìpẹ́ yìí ni wọ́n ti ń jíròrò bí òun ṣe lè ṣe ayẹyẹ náà.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ láti Harare, ó ní àbúrò òun obìnrin ló dàgbà jù nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tí wọ́n bí, òun sì ni wọ́n kà sí “olùgbámọ́ òbí” nínú ìdílé náà.

“Láti ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni a ti ń rẹ́rìn-ín nípa ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ogójì ọdún fún un, ṣùgbọ́n ó sọ pé òun ti ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ohun tí òun fẹ́”, ló sọ.

“Lẹ́yìn gbogbo ìjàkadì náà, ó rí gbogbo ohun tó ń fẹ́, nítorí náà, ó fẹ́ ṣe ayẹyẹ kan ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́”.

Ọ̀rẹ́ Dókítà Gomo, Angela Machonesa, kọ̀wé lórí Facebook pé àwọn jọ lọ síléèwé àti yunifásítì ní Zimbabwe, àti pé ikú rẹ̀ ba òun nínú jẹ́.

Ó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tó ní nínú kíláàsì kò ju ti ìmọ̀lára lọ. Ti o jẹ́ irú ẹni téèyàn máa ń lọ bá nígbà tó bá nílò ìfòyemọ̀, kì í ṣe ti èrò orí nìkan, àmọ́ ti ọkàn.

“Iroyin yii bà wá nínú jẹ́ gan-an. Inú ń bí wa. A ò mọ ibi tá a máa lọ. Àmọ́, ohun kan náà làwa náà ń sọ, ìyẹn ni pé, Fortune Gomo ṣe pàtàkì. Ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe pàtàkì. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ogún rẹ̀ láé”.

A ti bẹ̀rẹ̀ sí kó owó jọ ní ìlú Dundee láti kó owó jọ fún ìdílé Dókítà Gomo àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdòdó tí wọ́n fi rúbọ ni wọ́n fi sílẹ̀ níbi ikú rẹ̀ ní South Road.

Ìsọfúnni kan tí wọ́n so mọ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé náà sọ pé:

“Ó yà wá lẹ́nu gan-an pé irú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀ ládùúgbò wa. Kí àwọn áńgẹ́lì máa ṣọ́ ẹ”.

Lẹ́yìn tí Dókítà Gomo kúrò ní Zimbabwe, ó lọ kàwé ní Netherlands. O lo ọdun mẹwa to kọja lati tẹsiwaju iṣẹ ẹkọ ati iṣẹ amọdaju rẹ ni UK.

Many-bunches-of-flowers-were-being-left-in-South-Road-in-the-Lochee-area-with-messages-expressing-sadness-and-shock-at-Dr-Gomos-death

Ọ̀pọ̀ búùkù odòdó ni wọ́n ń fi sílẹ̀ ní South Road ní agbègbè Lochee, pẹ̀lú àwọn ìfiranṣẹ́ tí ń ṣàfihàn ìbànújẹ̀ àti ìyàlẹ́nu nípa ikú Dr. Gomo. BBC

O lo ọpọlọpọ ọdun ninu iwadii ti o ni ibatan si omi lẹhin ti o pari dokita rẹ ni awujọ ati imọ-ẹrọ ayika ni Ile-ẹkọ giga ti Dundee.

Ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ alákòókò-kíkún fún Scottish Water gẹ́gẹ́ bí ògbóǹkangí olùṣètò ohun àmúṣọrọ̀.

“Onímọ̀ sáyẹ́nsì tó ta yọ”Simon Parsons, olùdarí ètò àyíká ní ilé-iṣẹ́ Scottish Water, fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ilé-iṣẹ́ náà hàn sí ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Ó ní: “Fortune jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó tayọ, ó sì tún jẹ́ ògbóǹkangí nínú ètò bí omi ṣe ń lọ sí ní Dundee, níbi tó ti di ara ẹgbẹ́ wa ní oṣù February, ó sì ti di ọ̀kan lára àwọn tó wúlò gan-an tó sì ní ọ̀wọ̀ nínú ẹgbẹ́ wa”.

Àwọn ọlọ́pàá sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ ògbóǹkangí ló ń ran ìdílé Dókítà Gomo lọ́wọ́.

Olùwádìí Peter Sharp, tó ń darí ìwádìí náà, sọ pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò sí ewu kankan fún aráàlú.

Ẹnikẹ́ni tó bá ní àlàyé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni a bèèrè láti kàn sí Ọlọ́pàá Scotland.

Oriisun: BBCNEWS 

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment