Ọkùnrin kan lu ìyàwó rẹ̀ pa ní Ekiti
Obìnrin kan tí a mọ̀ sí Modupe Alasin kú lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ lù ú ní Efon Alaaye, Ìpínlẹ̀ Ekiti nítorí pé ó péjú sí oko.
Ìwé ìròyìn Vanguard sọ pé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí kan tí kò fẹ́ kí orúkọ òun di mímọ̀ ṣe sọ, obìnrin náà ń pariwo, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú bí ọkọ rẹ̀ ṣe ń nà án léraléra.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, ọkùnrin náà pàṣẹ fún obìnrin náà pé kó lọ fa omi nínú odò tó wà nítòsí, àmọ́ obìnrin náà ṣubú lulẹ̀, ó sì kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà nítorí àìlera.
Nígbà tí wọ́n kàn sí ọ̀gá tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìlú ní ìpínlẹ̀ Ekiti, SP Sunday Abutu, ó jẹ́rìí sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ pé wọ́n ti mú ọkọ náà fún ìwádìí síwájú sí i.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua