“Ọkọ mi kì í ṣe aṣírí” – Ruth Kadiri
Ruth Kadiri lórí fifi ìgbéyàwó rẹ̀ pa mọ́, Ọkọ mi kì í ṣe aṣírí bẹẹni igbeyawo mii ki se asiri
Òṣèré Nollywood tó lókìkí, Ruth Kadiri, ti fèsì ní kedere sí àwọn àsọyé tó ń tàn káàkiri pé ó ń fi ọkọ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Ezerika, pamọ́ kúrò lára àwọn èèyàn.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan lórí Dear Ife podcast tó jẹ́ ti Diary of a Naija Girl, Kadiri ṣàlàyé pé kò fi ìgbéyàwó òun pamọ́ nítorí àṣírí kan, ṣùgbọ́n torí pé òun kàn fẹ́ yẹra fún wàhálà àti ìrògbọ̀nṣọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìyá ọmọ méjì náà ṣe sọ, ọkọ rẹ̀ kópa nínú ìgbésí ayé òun lójú gbogbo èèyàn, tó fi mọ́ pé wọ́n máa ń lọ sí àwọn ayẹyẹ pa pọ̀.
Ó tún ṣàlàyé pé ọkọ òun jẹ́ ẹni tí kì í fẹ́ ìfarahàn púpọ̀. Ó fi ìdàrúdàpọ̀ hàn lórí ìdí tí àwọn èèyàn fi ń retí pé kí òun máa fi ìgbéyàwó òun hàn sí gbangba.
Ó ní:
“A máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀, a máa ń lọ sí àwọn ayẹyẹ pọ̀, ìgbésí ayé mi kì í ṣe àṣírí bí àwọn èèyàn ṣe rò. Ní gbogbo àwọn ayẹyẹ tí mo bá ṣètò, ọkọ mi máa ń wà níbẹ̀.”
“Fún ìṣàlàyé tó yè kooro, ọkọ mi kì í ṣe àṣírí. Àwọn tí wọ́n mọ̀ mí, wọ́n mọ̀ ọ́n. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó ti tó mi. Mi ò mọ̀ ìdí tí mo fi ní jókòó, tí màá sì máa rò pé, kí ni mo fẹ́ fi hàn?”
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua