Ọ̀gá Àwọn Tó ń Se Oògùn Olóró ni Ecuador, Fito Ni Wọ́n Ti Gbe Lọ Sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn alágbára kan ní Ecuador, Adolfo Macías Villamar, ni wọ́n ti fàṣẹ ọba mú lọ sí Amẹ́ríkà láti kojú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣòwò oògùn olóró àti ohun ìjà.
A mọ̀ ọ́n sí “Fito”, wọ́n tún mú un ní oṣù kẹfa, èyí tó lé ní ọdún kan lẹ́yìn tó sá kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọn dá fún àwọn ìwà ọ̀daràn kan.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ fún Reuters pé yóò farahàn ní ilé-ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ Amẹ́ríkà ní ọjọ́ Aje, níbi tí yóò ti jiyàn pé kò jẹ̀bi sí àwọn ẹ̀sùn kariayé ti gbígbé oògùn olóró àti ohun ìjà lọ́nà àìtọ́.
Macías jẹ́ olórí ẹgbẹ́ Los Choneros, èyí tí ó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn àjọ ọ̀daràn alágbára láti Mexico àti Balkans.
Wọ́n tún fura sí i pé òun ló pa olùdíje ààrẹ, Fernando Villavicencio, láṣẹ ní ọdún 2023.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan Los Choneros fún yíyí Ecuador padà láti ibi tí àwọn arìnrìn-àjò ti ń gbádùn sí orílẹ̀-èdè kan tí ó ní ìwọ̀n ìpànìyàn tí ó ga jù lọ ní agbègbè náà.
Ó lé ní ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo kokéènì tí wọ́n ń ṣe láyé ló ń gba àwọn èbúté Ecuador kọjá. Orílẹ̀-èdè yìí wà láàárín orílẹ̀-èdè méjì tó ń ta kokéènì jáde jù lọ lágbàáyé, ìyẹn orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà àti Peru.
Ní oṣù June, àwọn ọlọ́pàá rí Macías níbi tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ibi ààbò abẹ́lẹ̀ nísàlẹ̀ ilé olówó iyebíye kan ní ìlú Manta.
Wọ́n mú un lọ sí La Roca, ìyẹn ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí wọ́n ti ń ṣọ́ ọ gan-an. Ní àkókò náà, Ààrẹ Ecuador, Daniel Noboa yìn àwọn aláàbò fún jíjèrè rẹ̀, ó sì sọ pé wọn yóò mú un lọ sí Amẹ́ríkà.
Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀-èdè náà sọ pé wọ́n mú un kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ecuador ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday láti fi lé àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́wọ́.
“Ọ̀gbẹ́ni Macías àti èmi yóò fara hàn lọ́la níwájú ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ ní Brooklyn… níbi tí yóò ti sọ pé òun kò jẹ̀bi”, agbẹjọ́rò rẹ̀, Alexei Schacht, sọ fún Reuters. “Lẹ́yìn náà, a óò gbé e sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí a kò tíì sọ ibi tó wà”.
Àwọn ará Ecuador dìbò láti fàyè gba fífi àwọn aráàlú léni lọ́wọ́ nínú ìdìbò tí Ààrẹ Noboa pè, ẹni tó ṣèlérí láti gbógun ti ìwà ọ̀daràn tó ń pọ̀ sí i.
Ní oṣù kẹta ọdún yìí, Noboa sọ fún BBC pé òun fẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà, Yúróòpù àti Brazil dara pọ̀ mọ́ òun nínú “ogun” òun lòdì sí àwọn ẹ̀yà ọ̀daràn.
Orisun: BBC
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua