Nvidia n se Agbekalẹ Ẹ̀rọ Ìṣeẹ̀dá-ọpọlọ-ènìyàn Tí ó Lágbára síi fún China
A ti gbo ròyìn pé àjọ Nvidia ń ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ìṣe-ẹ̀dá-ọpọlọ-ènìyàn tuntun kan fún China, tí ó lágbára ju ẹ̀rọ H20 tí wọ́n ń tà fún orílẹ̀-èdè náà lọ.
Orúkọ tí wọ́n pè é fún ìgbà díẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn ṣe sọ, ni B30A.
Ní oṣù kẹrin, Ẹka Ìṣòwò ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fagi lé títà àwọn ẹ̀rọ H20 ti Nvidia fún China, níbi tí wọ́n ti sọ pé ó ṣe pàtàkì láti dáàbò bo “ààbò orílẹ̀-èdè àti ti ètò ọrọ̀-ajé.”
Lọ́dún tó kọjá, Nvidia jẹ́ nǹkan bí Dọ́là Bílíọ̀nù 17 láti ọjà China — èyí jẹ́ nǹkan bíi 13% owó wọn tí wọ́n kó wọlé lápapọ̀. Ṣùgbọ́n ìdènà títà ọjà sí ìta tí ìṣàkóso ìjọba Trump ṣe ní oṣù kẹrin fi wọ́n sínú ìṣòro, wọ́n sì pàdánù owó tó jẹ́ Dọ́là Bílíọ̀nù 5.5 lórí àwọn ohun èlò H20 tí wọ́n kò lè tà, wọ́n sì sọ pé àwọn máa pàdánù owó tó jẹ́ bílíọ̀nù-bílíọ̀nù lára owó tí ó yẹ kí wọ́n rà.
Ìṣàkóso ìjọba Trump mú ìdènà rẹ̀ kúrò ní oṣù keje. Ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ara ìgbàwọ́kù ìjà tó gbòòrò sí i láàárín àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì, ṣáájú ìpàdé gíga tí ó ṣeé ṣe láti wáyé láàárín Trump àti Ààrẹ China, Xi Jinping, nígbà ìgbà-gbẹ́gbẹ́.
Tẹ́lẹ̀díẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kéde àdéhùn kan pé Nvidia àti ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ mìíràn, Advanced Micro Devices, yóò san 15% owó tí wọ́n bá kó wọlé láti àwọn títà wọn ní China, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san fún àṣẹ láti máa tà àwọn ẹ̀rọ wọn níbẹ̀.
Nínú gbólóhùn kan, Nvidia sọ pé, “A máa ń ṣe ìwádìí lórí àwọn ọjà oríṣiiríṣi, kí a lè múra sílẹ̀ láti díje bí àwọn ìjọba bá ti yọ̀ọ̀da. Gbogbo ohun tí a bá ṣe ní àṣẹ kíkún ti àwọn aláṣẹ tí ó yẹ, a sì ṣe é pẹ̀lú èrò láti jẹ́ kí àwọn èèyàn ó jẹ èrè nínú rẹ̀.” TVC
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua