Nasboi parí ìrinajò rẹ̀ láti bẹ̀ Davido fún ẹsẹ̀ orin kan
Lawal Nasiru Michael tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Nasboi ti parí ìpèníjà tí ó fún ara rẹ̀ láti rìnrìn àjò káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà kí Davido lè fi ẹsẹ̀ orin kan fún un nínú orin rẹ̀.
Nasboi, tó wà lábẹ́ ilé iṣẹ́ orin Eminent Transglobal Sounds Record Ltd, ti kọ́ orin púpọ̀, ti o sí ti kọrin pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórin olókìkí bíi 2Baba àti Falz nínú orin rẹ̀ tó ń jẹ́ Ashewo, ó sì jẹ́ olùdíje nínú ẹ̀ka Next Rated Artist ní Headies Awards tó gbẹ̀yìn.
Ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) yìí, tí ó jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà, olórin àti òṣèré adẹ́rìńpòṣónú kọ̀wé lórí ẹ̀rọ-ayélujára rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún, ọdún 2025 nípa iṣẹ́ rẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń fara wé Davido láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò orin rẹ̀ ṣùgbọ́n ó lọ sí gbee sita gẹ́gẹ́ bí i òṣèré aláwàdà.
Ní ọdún 2019, mo bẹ̀rẹ̀ sí fara wé Davido láti gba àfiyèsí rẹ̀ fún orin mi, ṣùgbọ́n àwọn fídíò náà fi mí hàn gẹ́gẹ́ bí òṣèré àwàdà.. (Ètò Ọlọ́run)
“Mo ti padà wá láti bẹ̀bẹ̀ lọdọ 001. Bùnmí ni ẹ̀bùn pẹ̀lú ẹsẹ orin kan Ọba.”
“ Èmi yóò máa kúnlẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ 36 fún ọjọ́ 36. Mo gbàdúrà pé kí àlá yìí ṣẹ. Ẹ jọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ Nasboi, ẹ kàn fi àmì @davido sára lójoojúmọ́ nígbà tí ẹ bá rí ìsọfúnni náà….”
“Ọjọ́ kini, Ìpínlẹ̀ Osun, ìpínlẹ̀ márùndínlógójì ló kù”
Ó tẹ̀síwájú láti kúnlẹ̀ kárí àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní Nàìjíríàláti rí i pé gbajúgbajà olórin Davido fi hàn nínú orin rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ó ti rí ìjàmbá burúkú kan nínú ìrìn-àjò rẹ̀, ó kọ̀wé pé
“fún mi, èyí ti tóbi ju ẹsẹ orin kan láti ọ̀dọ̀ Davido lọ.
Ìrìn-àjò yìí kò mọ sí orin nìkan mọ́. Ó ti di iṣẹ́ àdáni – láti fi hàn pé mo lè borí ìṣòro, dojú kọ ewu gidi, mo sì ṣì ń tẹ̀síwájú. Ó jẹ́ nípa ìfaradà.
Ó jẹ́ nípa fífi hàn àgbáyé, àti ara mi, pé nígbà tí mo bá ti fi ọkàn mi lé ohun kan, mo máa ń parí rẹ̀. Èmi yóò tẹ̀síwájú ìpolongo yìí kì í ṣe nítorí ìbànújẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí ìdí tí mo ní. Mo nírètí pé ẹnì kan níta yóò rí èyí, yóò sì ní ìgboyà láti tẹ̀síwájú, pẹ̀lú nígbà tí ọ̀nà bá nira.
A kì í fi ìrọ̀rùn dìde, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.
Lónìí, ó ti parí ìrìn-àjò rẹ̀ ní Abuja níbi tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ti péjọ yí i ká láti fi ìfẹ́ hàn án pẹ̀lú apanilẹ́rìn-ín gbajúgbajà, Brianjotter!
Ìbéèrè náà ṣì wà, ṣé David Adeleke (Davido) yóò fi ibeere rẹ̀ sẹ?
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua