Nàìjíríà Segun South Africa Pelu Ami Ayo Mẹ́jì Sí Ọ̀kan LAti De Ipele Asekagba Ife WAFCON
Àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons ti Nàìjíríà, ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, gbá Bayana Bayana ti South Africa pelú ayo méjì sí ọ̀kan láti rí àyè gbà sí ìparí ìdíje 2024 Women’s Africa Cup of Nations (WAFCON).
Àwọn góòlù tí Rasheedat Ajibade gbá ní ìlàbọ̀ ìkíní àti ti Alozie ní àkókò àfikún eré náà rí i dájú pé àwọn agbábọ́ọ̀lù aṣaju Afirika ti o tẹsiwaju ṣẹgun awọn alatako wọn.
Nàìjíríà gbá góòlù kan nípa pẹ́nalítì ní ìṣẹ́jú tó kẹ́yìn ìlàbọ̀ ìkíní nígbà tí Ajibade yí bọ́ọ̀lù sí inú àwọ̀n láti ibi pẹ́nalítì. South Africa dáhùn pẹ̀lú pẹ́nalítì kan ní ìlàbọ̀ kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti lu agbábọ́ọ̀lù South Africa kan nínú agbègbè tó ṣe pàtàkì ti Nàìjíríà.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n rò pé eré náà ń lọ sí ìṣẹ́jú 30 ti àkókò àfikún ní ìṣẹ́jú kẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún (94), Alozie gbá góòlù láti inú fírí kíkì láti rí i dájú pé Nàìjíríà yóò pàdé olúborí láàárín orílẹ̀-èdè tó gbàlejò, Morocco, àti Ghana ní ìlàjì ìparí kejì.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua