Nafisa Aminu, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tó gba ìdíje èdè Gẹ̀ẹ́sì káríayé, tó borí àwọn orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlọ́gọ́ta (69)
Nafisa Abdullah Aminu, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) láti ìpínlẹ̀ Yobe, ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ọmọ tó mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì jù lọ lágbàáyé níbi ìdíje TeenEagle Global Finals ọdún 2025 tó wáyé ní ìlú London, ní orílẹ̀-èdè United Kingdom.
Nafisa, tó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ Nigerian Tulip International College (NTIC), borí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) láti orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlaadorin (69), ìṣe tuntun tó ti gbé e ga sí àyè gbàgede ẹ̀kọ́ káríayé, tó sì fi ọlá fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìdíje TeenEagle jẹ́ ìdíje káríayé tó máa ń dánwò bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, bí wọ́n ṣe máa ń ronú jinlẹ̀, àti bí wọ́n ṣe máa ń gbafọ̀ dáadáa. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti orílẹ̀-èdè tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn tí kò sọ ọ́ ni wọ́n máa ń kópa nínú rẹ̀.
Ìṣẹ́gun Nafisa ni wọ́n fi ìfẹsẹ̀kúǹtẹ́lẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ olórí ìdílé rẹ̀, Hassan Salifu, tó sọ pé “ìfaradà, ìwà àmúgbìyànjú, àti ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ ni wọ́n fa àṣeyọrí rẹ̀.”
Gẹ́gẹ́ bí Leadership ṣe ròyìn, ó sọ pé, “Àṣeyọrí tó gbòòrò káàkiri àgbáyé láti ọ̀dọ̀ ọmọ wa kò lè ṣeé ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ tó nírọ̀wánú fún ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Gómìnà Mai Mala Buni, ẹni tó jẹ́ pé ìgbìyànjú rẹ̀ ti fi ọlá káríayé fún ìpínlẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa.”
Ó tún sọ pé Nafisa Aminu borí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti orílẹ̀-èdè tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, àṣeyọrí títayọ tó fi bí ó ṣe gbọ́n tó àti bí ó ṣe múra sílẹ̀ tó hàn.
Ìṣẹ́gun yìí ti mú ayọ̀ wá sí ìpínlẹ̀ Yobe àti yíká rẹ̀. Ìdílé rẹ̀ sì ti fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn sí Gómìnà Buni àti àwọn olùkọ́ ní NTIC fún ipa tí wọ́n kó nínú ìgbéga agbára Nafisa.
Ìdílé náà fi kún un pé, “Àṣeyọrí Nafisa jẹ́ ẹ̀rí agbára ìdókòwò ẹ̀kọ́. Ìfaramọ́ Gómìnà Buni kò yí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ nìkan pa dà, ṣùgbọ́n ó tún gbé ìpínlẹ̀ Yobe àti Nàìjíríà ga sí ipò àgbáyé.”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ń pè báyìí pé kí wọ́n fún Nafisa ní ìṣọlá ìpínlẹ̀ àti ti orílẹ̀-èdè, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló rí ìṣẹ́gun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì agbára ẹ̀kọ́ tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ṣùgbọ́n tí kò tíì lò.
Ẹnì kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀, tó sì láyọ̀, sọ pé, “Ó ti fún orílẹ̀-èdè wa ní ọlá, ó ti borí àwọn orílẹ̀-èdè tí èdè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn. Ìṣẹ́gun rẹ̀ fi ọ̀rọ̀ pàtàkì ránṣẹ́ pé: bí ìrànlọ́wọ́ bá tọ̀nà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà lè tayọ káàkiri àgbáyé.”
Orisun – Vanguard
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua