Mercy Chinwo Ati Ọkọ Rẹ̀ Bi Ọmọ Keji
Olórin ìyìn-ìhìnrere, Mercy Chinwo, àti ọkọ rẹ̀, Blessed Uzochikwa, ti bi omo kejì wọn.
Tọkọtaya náà ṣe ìfihàn ìròyìn náà ni orí ìkànnì wọn ní ojo Etì, wọ́n sì pín àwọn àwòrán alawọ̀ dud ati aláwọ̀ funfun tí o n fi ayọ̀ ati ọpẹ́ hàn.
Wọ́n kọ̀wé pé: “Oluwa ti se é léèkan si! O ti fi kún ayọ̀ wa… ó ti mú ẹ̀rín wa pọ̀ si… ó sì ti fi ẹ̀bùn iyebiye ti ọmọ kejì bọ́ wa lọ́jọ́.
View this post on Instagram
“A jẹ́wọ́: orúkọ Rẹ̀ yóò wà lórí ìran wa títí láé. Àwọn ìran tí yóò jáde lára wa yóò rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Nípasẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò jẹ́ ìbùkún, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì pè wá ni alábùkún. Fún ògo Ọlọ́run… Káàbọ̀, ẹ̀bùn wa iyebíye.”
Lẹ́hìn ìkéde náà, àwọn olólùfẹ̀ ati àwọn olórin ìyìn-ìhìnrere tún gbé àwọn ìkànnì wọn kún fún àwọn ìwé-oriire ati àwọn àdúrà fún ẹbí náà.
Mercy ati Blessed se ìgbéyàwó ni oṣù Kẹjọ ọdún 2022. Wọ́n gba ọmọ àkọ́kọ́ wọn, Charis, wọlé ni oṣù Kẹwa ọdún 2023, wọ́n sì n se ayẹyẹ wiwa ọmọ kejì wọn ni kò ju ọdún méjì lẹ́hìn ìgbéyàwó wọn.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua