maltina

MALTINA TI BẸ̀RẸ IDÌJẸ ỌDÚN 2025 FÚN ÀWỌN OLÙKỌ́ PẸ̀LÚ Ẹ̀BÙN

 

MALTINA TI BẸ̀RẸ IDÌJẸ ỌDÚN 2025 FÚN ÀWỌN OLÙKỌ́ PẸ̀LÚ Ẹ̀BÙN N51.6m


Ni ayé tí àwọn olùkọ́ máa ń ṣiṣẹ́ ti o lágbára láì sí ìtẹ́wọ́gbà tó yẹ, Maltina ti tún ṣe àfihàn pé àwọn mọ̀yi iṣẹ́ olùkọ́ ní Nigeria.

Idije Maltina Teacher of the Year 2025 ti tún bẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú apò ẹ̀bùn tó tó N51.6 million, láti san owó ìyìn fún àwọn olùkọ́ tó ń ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ wọn.

Idije yìí, tó jẹ́ ti Nigerian Breweries-Felix Ohiwerei Education Trust Fund, ti di ohun pataki gan-an lórílẹ̀-èdè wa. Gbogbo olùkọ́ ní ile-ékó sekọ́ndírì, Bó jẹ́ ti ìjọba tàbí aládàáni, lè kópa.

Olùṣégun ni yóò gba N10 million, irin-ajo amọ̀ràn lọ si òkè òkun, àti iṣẹ́ amúlùwàbí tó tó N30 million fún ilé-ékó rẹ̀. Àwọn olùkọ́ míì náà yóò gba èrè owó àti àmì ìyìn gẹ́gẹ́ bí ìbáṣepọ̀ wọn.

Uzodinma Odenigbo, Olùdarí Ọ̀rọ̀ Ìbáṣepọ̀ lórí iṣẹ́ agbari ni Nigerian Breweries, sọ pé: “Idije yìí kì í ṣe kàn fún ìyìn, ó tún jẹ́ ọ̀nà tí a fi ń yí ayé àwọn olùkọ́ padà. A ti rí i pé àwọn tó ti gba ààmì ṣáájú ti mú ìmúlò yíyípadà bá ilé-ékó àti àdúgbò wọn.”

Ìforúkọsílẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti Osu Kefa, Ojo Kerinlelogun (June 24) títí di Oṣù Kẹjọ Ọjọ́ Kejìlélọ́gun (August 22). Gbogbo olùkọ́ tó bá fẹ́ kópa lè lọ sí ojú-òpó Maltina Teacher of the Year láti fi fọ́ọ̀mù sílẹ̀.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment