Leeds United fi Ọwọ́ Òsì Jùwe Ilé Bàbá Everton Fún
Leeds United, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ padà wá sí Premier League láti Championship, ti borí ìdíje àkọ́kọ́ wọn lónìí pẹ̀lú góòlù ìbọn tí wọ́n gbà.
Leeds lo gbogbo ipá wọn láti gba pọ́ìntì mẹ́ta lọ́wọ́ Everton lónìí, wọ́n jẹ gàba lórí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ́ẹ̀pẹ́ títí di ìparí rẹ̀.
Nínú ìdíje tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Daniel Farke ti jẹ gàba lórí bọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì ní ànfààní góòlù púpọ̀, wọ́n wá rí èrè wọn ní ìṣẹ́jú kọkànlélọ́gọ́rin (81) nígbà tí wọ́n fìyà jẹ́ James Tarkowski fún gbígbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú ọwọ́.
Eni tí wọ́n gbé wọlé gẹ́gẹ́ bí àfikún, gbá bọ́ọ̀lù ìbọn náà wọlé pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
Leeds ni ó fi ìdẹra léwájú jù lọ láti ìbẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú Joel Piroe, Wilfried Gnonto, àti Ao Tanaka tí wọ́n gbìyànjú láti gbà Jordan Pickford ní góòlù, nígbà tí Everton tiraka láti gba bọ́ọ̀lù dáadáa.
Fún Leeds, ìbẹ̀rẹ̀ tí ó dára jù lọ ni ó jẹ́ fún wọn nígbà tí wọ́n padà sí ibi ìdíje àwọn tó wà ní ìpele àgbà, wọ́n gba pọ́ìntì mẹ́ta àti pé wọn kò gbà wọ́n ní góòlù lójú àwọn olólùfẹ́ wọn tó pọ̀ ní ilé.
Everton, ní ọwọ́ kejì, fi ìbànújẹ́ kúrò ní West Yorkshire, wọn kò ṣe ohunkóhun tó dára níwájú, àṣìṣe ìgbèjà kan sì jẹ́ kí wọ́n pàdánù ní àkókò tó ṣe pàtàkì.
Ìṣẹ́gun yìí kò wulẹ̀ fún Leeds ní ìbẹ̀rẹ̀ tó dára nìkan, ó tún fi agbára àti ìdákọ́wọ́lú tí Daniel Farke ti kọ́ wọn hàn.
Everton kò lè dá góòlù kan ṣoṣo yẹn padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbábọ́ọ̀lù tó dára wà fún wọn nínú pápá, wọ́n dà bí ẹni tí kò mọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe níwájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí Leeds United FC fi hàn.
Nínú ìdíje Ọ̀sẹ̀ 2 tí ń bọ̀, Leeds United yóò kojú Arsenal FC nígbà tí Everton yóò kojú Brighton.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua