JAMB Kede Máàkì Fun Gbigba Wọlé Sí Fásítì
JAMB Ti Fi 150 Sí Máàkì Tó Kere Jù Lọ Fun Gbigba Wọlé Sí Fásítì Kan
Ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ètò gbígba akẹ́kọ̀ọ́ wọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà, JAMB (Joint Admissions and Matriculation Board), ti fi máàkì 150 kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí máàkì tó kéré jù lọ tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ní kó tó lè rí gbà wọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ìyẹn fásítì, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìpinnu yìí wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun níbi ìpàdé àgbáyé kan tó wáyé ní Bola Ahmed Tinubu International Conference Centre nílùú Abuja, tó jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ètò ẹ̀kọ́ gíga ló wà níbẹ̀.
Àwọn Máàkì To Kéré Jù Lọ Fún Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Mìíràn:
- Ilé Ẹ̀kọ́ Fásítì (Universities): 150
- Ilé Ẹ̀kọ́ Polytechnic: 100
- Ilé Ẹ̀kọ́ Olùkọ́ (Colleges of Education): 100
- Ilé Ẹ̀kọ́ Nọ́ọ̀sì (Colleges of Nursing Sciences): 140
- Ilé Ẹ̀kọ́ Ìgbìnwòkò (Colleges of Agriculture): 100
JAMB sọ èyí jáde lórí ojú-ìwé X (tí a mọ̀ sí Twitter tẹ́lẹ̀) wọn lẹ́yìn ìpàdé náà.
Ìdàgbàsókè yìí wáyé ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí JAMB fara gba pé àwọn ìṣòro kan wà nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ́ lásìkò ìdánwò UTME 2025. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n tún ṣètò ìdánwò mìíràn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kan káàkiri orílẹ̀-èdè.
Òfin Ọjọ́-Ìbí Kéré Jù Lọ Fún Wíwọlé Sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga
Ní àfikún, Ìjọba Àpapọ̀ ti fi ọjọ́-ìbí tí kò gbọ́dọ̀ kéré sí ọdún mẹ́rìndinlogun (16) kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́-ìbí tó kéré jù lọ tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ní kó tó lè wọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà.
Mínísítà fún ètò Ẹ̀kọ́, Tunji Alausa, ni ó kéde èyí ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun kan náà níbi Ìpàdé Àgbáyé lórí Ètò Gbigba Akẹ́kọ̀ọ́ Wọlé.
Wọ́n máa fi òfin ọjọ́-ìbí yìí sára láti inú ètò wọn, CAPS (Central Admissions Processing System), wọn yóò sì gbìyànjú láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ti pé ọmọ ọdún mẹ́rìndinlogun (16) títí di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ, ọdún 2025 láyè láti wọlé.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua