K1, Keyamo ati ValueJet

Ìwà KWAM 1 kò bójú mu – Keyamo

Last Updated: August 7, 2025By Tags: , , ,

Mínísítà fún ọ̀ràn ìṣèdèdéeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú, Festus Keyamo, ti da ìwà olórin fújì, King Wasiu Ayinde Marshal, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí KWAM 1, lẹ́bi, nítorí ìjà rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú ValueJet ní Papa ọkọ̀ òfurufú Àgbáyé ti Nnamdi Azikiwe, ní Abuja.

Mínísítà náà fi ìwà olórin fújì náà wé “ìwà tí kò setẹ́wọ́ gbà” àti “dìdà ènìyàn lagara.”

Nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó fi sílẹ̀ ní ọjọ́bọ̀, Keyamo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìròyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú, ó sì ti yẹ àwọn àwòrán fídíò wò nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹjọ, ọjọ́ karùún, ọdún 2025, èyí tí ó fi hàn pé KWAM 1 dí ọkọ̀ òfurufú ValueJet lọ́nà.

Ó sọ pé, “Kò bá ohun tí àwọn aṣojú Kwam 1 sọ mu, ó máa ń yí ipò rẹ̀ padà ní pápá ọkọ̀ òfurufú láti dí ọkọ̀ òfurufú náà lọ́nà láti kúrò fún ìgbé ọkọ̀ náà lọ.

Keyamo sọ pé, “Èyí jẹ́ ìwà tí Kò TẸ́WỌ́ GbÀ pátápátá.” “Dídí ọkọ̀ òfurufú náà lọ́nà láti kúrò nìkan ni ìwà tí kò yẹ yìí, tí ó jẹ́ bí ìgbà tí wọ́n ti ènìyàn mọ́.”

Keyamo tún fi àbùkù kàn balógun àti awakọ̀ ọkọ̀ òfurufú náà fún lílọ síwájú sí dí ojú-ìjàm̀bá láìfi ìbẹ̀rù hàn fún ààbò, ó sì sọ pé àwọn méjèèjì ti rú àwọn ìlànà ààbò tí International Civil Aviation Organisation (ICAO) gbé kalẹ̀.

Ó sọ pé, “Kò sí ìgbéraga tó yẹ kí ó mú balógun àti awakọ̀ ọkọ̀ òfurufú bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò níbi tí ó wà láìgbà wá ní ìdánilójú pé àwọn ọlọ́pàá ti mú ẹni tí kò wà létò lọ.”

Nígbà tí ó ń yìn Nigeria Civil Aviation Authority (NCAA) fún dídá ìwé-aṣẹ́ awakọ̀ náà dúró títí wọ́n fi ṣe ìwádìí, mínísítà náà kà á sí àdánilẹ́bi fún gbígbé ìgbésẹ̀ onígbèéraga, ó sì pa á láṣẹ́ pé kí ilé-iṣẹ́ náà fi KWAM 1 sínú àkójọ àwọn tí a kò gbọdọ̀ gba sínú ọkọ̀ òfurufú.

Keyamo sọ pé, “Ohun tí ó kan gbóko, ó gbọ́dọ̀ kan gbojù. Gbogbo àwọn ọkọ̀ òfurufú, àwọn tí ó wà ní ilé àti àwọn tí ó wà ní òkè-òkun, ni wọ́n gbọ́dọ̀ gba ìsọfúnni lẹsẹ̀kẹsẹ̀ nípa àṣẹ yìí, ẹnikẹ́ni tí ó bá rú àṣẹ yìí, yóò pàdánù ìwé-aṣẹ́ iṣẹ́ wọn.”

Orisun – Vanguard

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment