EFCC mu awon afurasi

Ìwà-Jẹgúdùjẹrá: EFCC Mú Àwọn Àfúrásí 36 Lórí Ìwà-Jẹgúdùjẹrá lórí Ayélujára Ní Port Harcourt

Last Updated: August 20, 2025By Tags: , , ,

Àwọn òṣìṣẹ́ ti Olùdarí Àgbègbè Port Harcourt ti Ìgbìmọ̀ fún Ìdènà Àwọn Ìwà-jẹgúdùjẹrá nípa Owó (EFCC), ti mú àwọn ènìyàn 36 tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ajẹgúdùjẹrá lórí ẹ̀rọ ayélujára ní Port Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers.

Wọ́n mú wọn ní Ọjọ́ Kẹ́sẹ́, Oṣù Kẹjọ, ọdún 2025, nípa ìgbòkègbodò àṣírí kan ní àwọn àgbègbè oríṣiríṣi ní Port Harcourt lẹ́yìn ìwádìí tó gbékè lé nípa ìfẹ́sùn kàn wọ́n lórí ìwà-jẹgúdùjẹrá tó jẹ mọ́ ẹ̀rọ ayélujára.

EFCC mu awon afurasi

EFCC mu awon afurasi

EFCC mu awon afurasi

Àwọn nǹkan tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ wọn ni àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ oníyebíye oríṣiríṣi, alùpùpù Q-link, àwọn ẹ̀rọ amóhùn-máwò-rán àti kọ̀mpútà oríṣiríṣi tí ó ní àwọn ìwé tó fi hàn pé wọ́n jẹ̀bi àti àwọn ìwé èké.

A óò pe àwọn àfúrásí náà lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìwádìí.

EFCC mu awon afurasi

EFCC mu awon afurasi

EFCC mu awon afurasi

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment