Ìpínlẹ̀ Èkó bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ tuntun fún ilé tó wà nínú ewu
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìforúkọsílẹ̀ tuntun láti fi kún àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ aláìní àti aláìlágbára tí kò sí nínú àkójọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ ìjọba tẹ́lẹ̀.
Ìgbésẹ̀ yìí wà lára àwọn ìsapá láti dín òṣì kù àti láti mú àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn lágbára káàkiri ìpínlẹ̀ náà.
Ìforúkọsílẹ̀ náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Àgbègbè Ìdàgbàsókè (CDA) Ajibola ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Ikosi-Isheri (LCDA), ni ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìfowósílẹ̀ àti ìnáwó, ìyẹn Ministry of Economic Planning and Budget, lábẹ́ ìdarí Kọmíṣọ́nà Ope George, ló ń bójútó.
Níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ náà, Olùdarí fún Ẹ̀ka Tó ń Bójútó Ètò Ìrànlọ́wọ́, Ìyáàfin Oluwakemi Garbadeen-Adedeji—tí ó dúró fún Akọ̀wé Títíláé, Ìyáàfin Olayinka Ojo—tún fi ìdí ìfaramọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ múlẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ lóòótọ́.
Garbadeen-Adedeji sọ pé, “Ìforúkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì láti fi de ibi àfojúsùn wa láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ìdílé aláìní àti aláìlágbára,” ó sì sọ pé ìforúkọsílẹ̀ náà yóò ran ìjọba lọ́wọ́ láti mọ àwọn tí wọ́n kò kà sí nínú àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́.
Alága fún Àgbègbè Ìdàgbàsókè Ajibola, Alhaja Arikawe Adewale, yin Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fún bí ìjọba rẹ̀ ṣe fọkàn sí ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn. Ó ṣàpèjúwe ètò náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn èrè ìjọba tiwa-n-tiwa tí ó hàn gbangba, ó sì rọ àwọn òṣìṣẹ́ láti sọ fún ìjọba bí àwọn ará àdúgbò ṣe fún ìgbésẹ̀ yìí lọ́wọ́ pẹ̀lú ìfaramọ́ ńlá.
Ìforúkọsílẹ̀ yìí jẹ́ àbájáde ìdàpọ̀ àkójọpọ̀ orúkọ àwọn tí ìrànlọ́wọ́ Ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State Single Social Register – LASSR) pẹ̀lú Nọ́ńbà Ìdánimọ̀ Orílẹ̀-èdè (National Identification Number – NIN), tí ó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹrin, ọjọ́ kẹsàn-án, ọdún 2025, kákiri gbogbo Ìjọba Ìbílẹ̀ mẹ́tàdínláàádọ́ta (57) àti àwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ LCDA.
LASSR, tí ó jẹ́ apá kan àkójọpọ̀ Orílẹ̀-èdè, jẹ́ àkójọpọ̀ pàtàkì tí ìjọba máa ń lò láti mọ àwọn ìdílé aláìní àti aláìlágbára ní ìpínlẹ̀ láti fi ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn.
Gẹ́gẹ́ bí Ilé-iṣẹ́ Tó ń Bójútó Ètò Ìfowósílẹ̀ àti Ìnáwó ṣe sọ, àfojúsùn àtúnṣe ìforúkọsílẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni láti rí i dájú pé gbogbo àwọn ìdílé tí ó tọ́ sí i ni wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀ dáadáa, kí wọ́n sì lè jàǹfààní lára àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ ìjọba, nípa báyìí, yóò mú kí ìpín ìrànlọ́wọ́ náà wá lọ́nà tó tọ́ àti tó munádóko ní Èkó. – Vanguard
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua