Ipari Ọ̀nà fun Junior D’Tigress ni FIBA U19 World Cup

Last Updated: July 17, 2025By Tags: , ,

Nàìjíríà Jáde Nínú FIBA U19 World Cup Bi Ẹgbẹ́ Bọ́ọ̀lù Orílẹ̀-Èdè Hungary Bori D’Tigress Kékere.

Ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù aláfowogba ti Hungary bori D’Tigress Kékere tí Nàìjíríà pẹ̀lú àmì 77-51 ní Ọjọ́rú, èyí sì mú kí Nàìjíríà jáde kúrò nínú ìdíje FIBA U19 Women’s Basketball World Cup tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Czechia.

Ilé-iṣẹ́ Agbéròyìn ti Nàìjíríà (NAN) ròyìn pé àwọn ọmọbìnrin Nàìjíríà ni àwọn ọ̀tá wọn borí pátápátá bí wọ́n ṣe tiraka jálẹ̀ ìjàkadì náà.

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára, wọ́n sì gba àmì 9-9 ní ìpín àkọ́kọ́ eré náà, ṣùgbọ́n wọ́n fọ́ yángá ní ìpín kejì, wọ́n sì padà pẹ̀lú àmì 12-30.

Ẹgbẹ́ náà gbìyànjú láti borí ní ìpín kẹta ṣùgbọ́n wọ́n kàn lè gba àmì 15-16, èyí tí kò tó láti fi ìyàtọ̀ hàn sí ẹgbẹ́ European náà.

Hungary gba ìpín kẹrin tokan tokan, wọ́n sì gba àmì 16-15 láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún iṣẹ́gun.

Kinga Jisepovits ti Hungary ló darí ẹgbẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àmì 19, nígbà tí akẹgbẹ́ rẹ̀ Eliza Farbas gba àwọn bọ́ọ̀lù tí ó já bọ́ lẹ́ẹ̀kan (rebounds) 13.

Tobenna Nweke ti Nàìjíríà ló darí pápá pẹ̀lú àmì 12, nígbà tí Francis Chukwu gba àwọn bọ́ọ̀lù tí ó já bọ́ lẹ́ẹ̀kan (rebounds) 9.

Àwọn ọmọbìnrin Nàìjíríà jáde kúrò nínú ìdíje náà, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹgbẹ́ Áfíríkà àkọ́kọ́ tí ó borí eré kan nínú ìtàn ìdíje náà, wọ́n sì tún kopa nínú ìpele mẹ́rìndínlógún.

Orisun: (VANGUARD)

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment