Inec logo

INEC Bẹ̀rẹ̀ Ìforúkọsílẹ̀ Olùdìbò Káàkiri Orílẹ̀-Èdè ní Ọjọ́ Kẹjidinlogun Oṣù Kẹjọ

Last Updated: August 1, 2025By Tags:

Àjọ Tí Ń Rí Sí Ètò Ìdìbò (INEC) ti sọ pé ìforúkọsílẹ̀ Olùdìbò Títí Lọ (CVR) fún ọdún 2025 yóò bẹ̀rẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè ní Oṣù Kẹjọ ọjọ́ kejidínlógún.

INEC kéde èyí lórí ojú ìwé X wọn lọ́jọ́ Ẹtì.

Àjọ náà sọ pé ìforúkọsílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ìkànnì ayélujára yóò bẹ̀rẹ̀ ní Oṣù Kẹjọ ọjọ́ kẹtàdínlógún nípasẹ̀ ojú ìwé ìkànnì àjọ náà, cvr.inecnigeria.org.

Ó sọ pé ìforúkọsílẹ̀ nípa gbígbé ara ẹni lọ sí àwọn ibùdó yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, ní Oṣù Kẹjọ ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n.

Èyí, ó sọ, ni yóò wáyé káàkiri orílẹ̀-èdè ní gbogbo àwọn ọ́fíìsì ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ tí wọ́n ti yàn.

INEC sọ pé a óò ṣe ìgbésẹ̀ náà láti ọjọ́ Àṣẹ́kù sí ọjọ́ Ẹtì, ó máa bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án àárọ̀ yóò sì parí ní aago mẹ́ta ìrọ̀lẹ́.

Ó sọ pé: “Ìdìbò rẹ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìforúkọsílẹ̀. Má ṣe fi àǹfààní rẹ sílẹ̀ láti forúkọ sílẹ̀.”

 

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment