Cowbell

Ìkìlọ̀ Lórí Ayéderú Miliki Cowbell “Our Milk” ní Nàìjíríà – NAFDAC

Last Updated: August 22, 2025By Tags: , , , ,

Àjọ Tó Ń Rí sí Ìṣàkóso Oúnjẹ àti Òògùn ti Orílẹ̀-èdè (NAFDAC) fi ìkìlọ̀ jáde ní ojo Eti, Oṣù Kẹjọ Ọjọ́ kẹjìlélógún, ọdún 2025, nípa ọjà Cowbell ayéderú tí wọ́n ti ń pín kiri.

Àjọ NAFDAC ń fún àwọn ènìyàn ní ìsọfúnni nípa wíwà àwọn ayéderú Cowbell “Our Milk” 12g tí wọ́n ń tà kiri ní Nàìjíríà.

Promasidor Nigeria Ltd, tí ó jẹ́ Ẹni tó ní Àṣẹ Ìpolówó Ọjà (MAH) àti ẹni tó ń ṣe Cowbell “Our Milk” ròyìn fún àjọ náà nípa wíwà ọjà kan tí ó jọ ọjà Cowbell “Our Milk” 12g gidi.

Èyí pẹ̀lú lílò orúkọ ọjà láìláṣẹ, àwòrán ìkópamọ́, nọ́ńbà ìforúkọsílẹ̀ NAFDAC, àti àṣẹ orúkọ ọjà. MAH ti fi múlẹ̀ pé àwọn ọjà wọ̀nyí kì í ṣe àwọn ni wọ́n ṣe tàbí pín, nítorí pé àwòrán ìkópamọ́ ayéderú yìí ni ilé-iṣẹ́ náà kẹ́yìn lò fún ìṣe ọjà ní Oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023.

Àwọn Ohun Tó Yẹ Kí a Mọ̀ Nípa Cowbell Milk 12g Tòótọ́ àti Ayéderú

  • Miliki Cowbell 12g tòótọ́ jẹ́ miliki tí ó ní èdò dáadáa, ṣùgbọ́n ayéderú kò rí bẹ́ẹ̀.
  • Ohun èlò tí wọ́n fi kó ọjà tòótọ́ ni àtúnṣe àwòrán PNG “Our Creamy Goodness,” nígbà tí èyí tí ayéderú jẹ́ àwòrán PNG àtijọ́ “Our Milk.”
  • Títẹ àwọn ìsọfúnni àgbájọ́ ọjà tòótọ́ ni wọ́n fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé oníná ṣe, nígbà tí ti ayéderú jẹ́ ìdánà ìtẹ̀wé lásán.

NAFDAC kìlọ̀ pé lílo tàbí mímu Cowbell “Our Milk” ayéderú léwu ńlá sí ìlera àti ààbò, nítorí pé irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ lè ní àwọn ohun èlò tó lè ṣe ni lára, bíi májèlé, àwọn àfikún tí a kò fọwọ́ sí, tàbí àwọn ohun èlò tí wọ́n ti pọn tí kò bá àwọn ìlànà ààbò oúnjẹ.

Mímu miliki ayéderú lè yọrí sí àwọn àrùn tí ó lè wá láti inú oúnjẹ, ohun tí ara kò gbà, ìbàjẹ́ ara, tàbí ikú pàápàá ní àwọn ipò tó le gan-an. Àwọn ọmọ ọwọ́, ọmọdé, àwọn aboyún, àti àwọn àgbàlagbà ni wọ́n lè fara gba nǹkan jù lọ.

Àwọn Àlàyé Nípa Ọjà

Àwọn àlàyé nípa ọjà ayéderú náà wà báyìí:

  • Orúkọ Ọjà: Cowbell Our Milk 12g
  • Ilé-iṣẹ́ tó sọ pé òun ni ó ṣe é: Promasidor Nigeria Ltd.
  • Ọjọ́ tí Wọ́n Ṣe É: 04 2025
  • Ọjọ́ tí Yóò Parí: 12 2028
Cowbell

Cowbell

Cowbell

Cowbell Fake

Wọ́n ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn olùdarí agbègbè àti àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀ NAFDAC láti wà lójú àmọ̀fíìntán kí wọ́n sì kó àwọn ọjà Cowbell 12g ayéderú wọ̀nyí lọ láàárín àwọn agbègbè àti àwọn ìpínlẹ̀ wọn.

A gbà àwọn ajìgbọ̀n, àwọn olùtà ọjà kékeré, àti àwọn olùlò ọjà níyànjú láti fi ìṣọ́ra àti ìwàfúra hàn láàárín ìlànà gbígba ọjà láti dènà pípín, títà, àti lílo ọjà miliki ayéderú náà. Ó yẹ kí a gba gbogbo àwọn ọjà oúnjẹ láti ọwọ́ àwọn ilé-iṣẹ́ tàbí àwọn ajìgbọ̀n tí ó ní àṣẹ.

Ó yẹ kí a yẹ ìwà tòótọ́ àti bí ara ọjà ṣe rí wò dáadáa.

A gbà àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àti àwọn olùlò ọjà níyànjú láti fi gbogbo afúrásí ìtán-títà àwọn ọjà oúnjẹ tí kò kúnjú òṣùwọ̀n àti ayéderú ròyìn fún ọ́fíìsì NAFDAC tí ó sún mọ́ wọn, tàbí NAFDAC lórí 0800-162-3322 tàbí nípa ìfiranṣẹ́ orí Ímẹ̀élì: sf.alert@nafdac.gov.ng

Bákan náà, a tún rọ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera àti àwọn aláìsàn láti ròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kùnà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú lílo àwọn ọjà oúnjẹ ayéderú fún ọ́fíìsì NAFDAC tí ó sún mọ́ wọn, tàbí nípasẹ̀ lílo àwọn ibi ìforúkọsílẹ̀ lórí ayélujára tí ó wà lórí ìkànnì NAFDAC www.nafdac.gov.ng tàbí nípasẹ̀ ìfiranṣẹ́ orí Ímẹ̀élì lórí: pharmacovigilance@nafdac.gov.ng.

 

 

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment